Ọpọ awọn to ri ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Sidney Holmes nini to ti n sunkun laipẹ yii, yoo mọ pe ibanujẹ nla lo jẹ fun un lati jiya ẹṣẹ ti ko mọ nnkankan nipa ẹ.
Sidney la gbọ pe wọn ju sẹwọn irinwo (400) ọdun lori ẹsun idigunjale niluu Florida.
Ọdun 1988 ni ọwọ tẹ Sidney, ẹsun ti wọn si fi kan an ni pe, o jẹ awakọ fun awọn ọkunrin meji kan ti wọn lọ ja obinrin kan ati ọkunrin kan lole niwaju ile itaja igbalode.
A gbọ pe niṣe ni wọn yọ ibọn si awọn mejeeji naa ko to di pe wọn ja wọn lole, nibẹ la gbọ pe wọn ti gba mọto ọkunrin naa, ti wọn si gbe e salọ.
Ọdun 1989 ni ọwọ tẹ Sidney, ti agbẹjọro igba naa si rọ ile ẹjọ lati sọ ọ sẹwọn ọdun 825, ṣugbọn ti ile ẹjọ foju aanu wo o lati juu sẹwọn irinwo ọdun.
Laipẹ yii ni wọn tun ẹjọ naa gbe yẹwo, ti aṣiri si pada tu sita wi pe Sidney ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan an.
Bi otitọ ṣe foju han ni ile ẹjọ paṣẹ pe ki wọn tu Sidney silẹ lati maa lọ layọ ati alaafia.
No comments:
Post a Comment