Lẹyin to lulẹ nibi idibo to kọja, Tolu Phillips, oludije lẹgbẹ oṣelu Labour darapọ mọ PDP lati ṣatilẹyin f'Adebutu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 4, 2023

Lẹyin to lulẹ nibi idibo to kọja, Tolu Phillips, oludije lẹgbẹ oṣelu Labour darapọ mọ PDP lati ṣatilẹyin f'Adebutu


Oludije s'ile igbimọ aṣofin kekere niluu Abuja lati ẹkun ijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour ninu eto idibo to waye lopin ọsẹ to kọja lọ, Ọnarebu Tolulọpẹ Phillips ti sọ pe oun ko le tẹsiwaju ninu ẹgbẹ ọhun mọ, lẹyin abajade esi ibo naa.

Tolulọpẹ Phillips lo sọ eyi di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja lakoko to n fi erongba rẹ han nipa idi ti ko fi le tẹsiwaju ninu ẹgbẹ Labour.

O ni oun ti ri ọjọ iwaju rere ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ati pe oun ṣetan lati ṣatilẹyin ibo fun oludije labẹ asia ẹgbẹ naa, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu ti ọpọ mọ si Lado.

Siwaju sii lo sọ pe gbogbo awọn ọmọ ẹyin ati alatilẹyin oun loun yoo ko wọnu PDP, ki erongba rere ti ẹgbẹ naa le, le jọ tẹ wọn lọwọ papọ.

Fọto bi nnkan naa ṣe lọ ree:





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI