Itan tuntun ni ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fi balẹ l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii nigba ti wọn ṣi opopona oni kilomita mọkanla le diẹ, iyẹn opopona Osi-Obbo si Aiyegunlẹ.
A gbọ pe lati bi aadọta ọdun ṣeyin lawọn ijọba to ti kọja lọ ti fi opopona naa jẹun, pẹlu bi wọn ṣe n gbe e f'awọn agbaṣẹṣe lọdọọdun lati ṣe e.
Orin ọpọ lo gba ẹnu awọn ara ipinlẹ naa nigba ti Gomina AbdulRazaq ṣi opopona naa pẹlu ariya rẹpẹtẹ.
Pẹlu idunnu ati ayọ nla ni Ọwa L’Obbo tiluu Obbo-Aiyegunle, Onimọ-ẹrọ Samuel Adelọdun fọkan AbdulRazaq balẹ wi pe oun yoo polongo ibo fun un lakoko idibo to n bọ lọjọ Abamẹta, Satide to n bọ lọhun.
Ninu ọrọ gomina, AbdulRazaq sọ pe idunnu nla lo jẹ foun wi pe opopona naa pari layọ ati alaafia, ati pe aṣeyọri nla lo jẹ wi pe nnkan tawọn eeyan ko nigbagbọ pe o le di ṣiṣe ti wa si imnuṣẹ loju araye.
No comments:
Post a Comment