Ifẹ Ọlọrun ni bi Dapọ Abiọdun ṣe jawe olubori - Macgregor - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 20, 2023

Ifẹ Ọlọrun ni bi Dapọ Abiọdun ṣe jawe olubori - Macgregor


Ọba tuntun ti wọn dibo yan niluu Orile-Ilawọ, ijọba ibilẹ Ọdẹda nipinlẹ Ogun, Oluṣẹgun Alexander MacGregor ti gbe oṣuba kare fun Gomina Dapọ Abiọdun lori bo ṣe jawe olubori ninu eto idibo to waye lopin ọsẹ to kọja yii.

Alakoso eto idibo to kede Dapọ Abiọdun, Ọjọgbọn Kayọde Adebọwale ti fasiti Ibadan lo kede Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi eni to jawe olubori lọjọ Aiku, Sannde ana niluu Abẹokuta.
 
Ọjọgbọn Adebọwale sọ pe ibo 276,298 ni Dapọ Abiọdun fi lewaju, nigba ti Ladi Adebutu ni ibo 262,383 fun ipo keji, ati Biyi Ọtẹgbẹyẹ toun ṣe ipo kẹta pẹlu ibo 94,754.

Ninu atẹjade to fi ki Gomina Abiọdun, MacGregor sọ pe ẹni ti Ọlọrun yan ni, to si lọ ni ibamu pẹlu ifẹ awọn araalu.

"A ni lati dupẹ fun Ọlọrun lori aṣeyọri eto idibo to waye kọja lọ yii, nitori pe ifẹ Ọlọrun pada wa si imuṣẹ lai ni wahala kankan ninu.

"Ipinnu awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ogun ni lo wa si imuṣẹ lori bi wọn tun ṣe pada dibo yan ẹni ti Ọlọrun ti yan fun wọn, ẹni to ti n ṣe ifẹ araalu loju mejeeji, to si ni loun nigbagbọ pe saa keji yii yoo mu ilọsiwaju gidi ba ipinlẹ Ogun.

"Mo ki Ọmọọba Dapọ Abiọdun ku oriire bo ṣe jawe olubori, nitori to fi han pe iṣẹ rẹ lo duro fun un niwaju awọn araalu. Bi kii ba a ṣe bẹẹ, ohun miran la o ba maa sọ.

"Ohun ti mo fẹẹ fi da awọn eeyan loju ni pe, igba ọtun ṣẹṣẹ bẹrẹ nipinlẹ Ogun ni, nitori pe Gomina Abiọdun yoo tẹsiwaju awọn akanṣe iṣẹ to ti n ba bọ lati ọdun mẹrin sẹyin, ti yoo si tun bẹrẹ awọn iṣẹ miran.

"Mo fẹẹ rọ gbogbo awọn alatako, paapaa awọn to padanu ninu eto idibo yii lati fọwọsowọpọ pẹlu Abiọdun, nitori pe nipa ifẹ ati iṣọkan ni ipinlẹ kan, tabi orileede le fi ni ilọsiwaju ati idagbasoke. Ẹ jẹ ka gbagbe ọrọ oṣelu nitori pe Gomina naa ti sọ pe oun ṣetan lati ba gbogbo wọn ṣiṣẹ papọ fun itẹsiwaju ipinlẹ Ogun.

"Gẹgẹ bi akọmọna Gomina Abiọdun ni gbogbo igba to sọ pe 'igbega ipinlẹ Ogun, a jọ ṣe gbogbo wa ni', eyi ni mo fẹ ki gbogbo araalu duro ti Gomina lati rii pe ipinlẹ yii dagbasoke yala nipa eto ọrọ aje, eto ẹkọ, ati igbayegbadun araalu."

Macgregor siwaju sii wa rọ Gomina Dapọ Abiọdun lati ma ṣe gbagbe ilu Orile-Ilawọ ati agbegbe ẹ, nipa iṣẹ akanṣe, to si ni ilu naa nilo idagbasoke, paapaa nipa opopona ati eto ọrọ aje.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI