Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun ti gbe oṣuba kare fun gbajugbaja ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited to tẹdo siluu Abẹokuta lori awọn idagbasoke ti wọn n mu ba ọrọ ile gbigbe n'ipinlẹ naa.
Akọwe agba lẹka ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ile gbigbe n'ipinlẹ naa, Ọgbẹni Kẹhinde Ọnasanya lo gbe oṣuba kare naa fun alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Pelican Valley, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ lori ipa to n ko lẹka eto ile gbigbe naa laipẹ yii.
Ọgbẹni Kẹhinde Ọnasanya sọ pe ijọba ipinlẹ Ogun mọ riri iṣẹ ti ileeṣẹ Pelican Valley n ṣe, to si jẹ ọkan pataki lara awọn ileeṣẹ to n ṣe iranwọ nla fun ijọba ipinlẹ naa, nipa ile gbigbe ati igbanisiṣẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe ijọba nikan ko le da ọrọ ile gbigbe, paapaa ohun t'awọn araalu nilo yanju tan, idi ree ti Gomina Dapọ Abiọdun ṣe n fun awọn ileeṣẹ ati olokoowo aladani ni koriya lati maa wa ọna iranwọ to le mu idẹrun ba araalu.
Ọnasanya lo sọrọ yii nibi abẹwo to ṣe lọ si ileeṣẹ Pelican Valley Estate to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii.
No comments:
Post a Comment