Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara ti sọ pe gbogbo ohun ti awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara ba n fẹ loun ṣe ni saa keji toun fẹẹ bẹrẹ yii.
AbdulRazaq lo sọrọ naa lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee lakoko to n gba iwe ẹri moyege lọwọ ajọ INEC, lẹyin to jawe olubori ninu eto idibo gomina to waye lopin ọsẹ to kọja lọ lọhun.
Yatọ si Gomina AbdulRazaq to gba iwe ẹri moyege naa, igbakeji rẹ, Kayọde Alabi ati gbogbo awọn to jawe olubori ninu eto idibo sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ni wọn tun gba iwe ẹri wọn.
AbdulRazaq sọ pe oun yoo jẹ eleti-i-gbọ ati olufọkansin araalu ninu eto iṣejọba saa keji yii, nitori pe awọon araalu ti fi han pe awọn ko fẹ lati tẹsiwaju mọ ninu iṣejọba okunkun ti wọn ti ni sẹyin.
Lara awọn to kọwọrin pẹlu Gomina AbdulRazaq lati lọ gba iwe ẹri naa ni iyawo rẹ, Ambassador Olufọlakẹ; awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ; Mutawali ilu Ilọrin, Ọmọwe Alimi AbdulRazaq; alaga APC, Ọmọọba Sunday Fagbemi; Baba AbdulRazaq, to fi mọ awọn oloye ẹgbẹ APC nipinlẹ naa.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Paul Ọdama to fi mọ awọn olori awọn oṣiṣẹ aabo ko gbẹyin nibẹ.
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti lo anfaani rẹ lati dupẹ lọwọ gbogbo awọn to dibo fun un patapata, to si loun ko ni ja wọn kulẹ ni saa keji iṣejọba oun.
Bakan naa lo pe gbogbo awọn alatako rẹ patapata lati fọwọsowọpọ pẹlu iṣakoso oun lati le mu ipinlẹ naa tẹsiwaju, nipa ifẹ, iṣọkan, paapaa eto ọrọ aje.
No comments:
Post a Comment