Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun l'ọjọ Aje, Mọnde, ana ti bu ọwọ lu Ọgbẹni Kọlawọle Fagbohun gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ ijọba n'ipinlẹ naa.
Fagbohun lo gba ipo lọwọ Ọmọwe Nafiu Aigoro, ẹni to fẹyinti lẹnu iṣẹ ijọba l'ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja yii.
Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Tokunbọ Talabi to jẹ akọwe ijọba ipinlẹ naa fi sita, o sọ pe Fagbohun ni oṣuwọn rẹ tun julọ, to si loun ni ipo ọhun tọ si, paapaa nipa afọkansin rẹ.
Talabi sọ pe Fagbohun lo gba awọọdu oṣiṣẹ ijọba to ṣe daadaa julọ lọdun 2007, nitori ifarajin rẹ si iṣẹ to gba.
Ki wọn to yan Fagbohun, oun ni akọwe agba lẹka ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ nipinlẹ Ogun, to si kopa to jọju nibẹ.
Ọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin, ọdun 1964 ni wọn bi Fagbohun, niluu Ilobi, ijọba ibilẹ Yewa South. O ni iwe ẹri B.Sc ninu ẹkọ eto oṣelu, (Political Science) ni fasiti Bẹnin lọdun 1988, bẹẹ lo ni M.Sc ninu eto ẹkọ Industrial Relations and Personnel Management to ṣe ni fasiti Ekoo lọdun 1995.
No comments:
Post a Comment