Eto isinku to jọju la maa fun Oloogbe Diya - Abiọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 28, 2023

Eto isinku to jọju la maa fun Oloogbe Diya - Abiọdun


Gomina Dapọ ABiọdun ti ipinlẹ Ogun ti kede sita wi pe ijọba ipinlẹ naa ni yoo gbe gbogbo bukata eto isinku Oloogbe Ọladipọ Diya, ẹni to ti figba kan ri jẹ olori awọn oṣiṣẹ olori orileede yii labẹ iṣakoso ologun, Oloogbe AJagunfẹyinti Sanni Abacha.
 
Abiọdun lo sọrọ naa lakoko to ṣabẹwo ibanikẹdun si mọlẹbi Ologbe naa nile rẹ to wa niluu Ekoo laipẹ yii.

O ni ipinlẹ Ogun ni yoo ṣagbatẹru eto isinku naa, lati le bu ọla ati iyi ikẹyin fun un, lati awọn ipa to ti ko ninu idagbasoke ipinlẹ Ogun, paapaa orileede Naijiria.
 
Lakoko to n sọrọ, o ni adanu nla ni iku ajagunfẹyinti naa jẹ fun orileede yii, nitori pe o ti kopa to jọju, pẹlu wi pe o jẹ aṣaaju rere ti iwa rẹ ṣee tẹle.
 
Bakan naa lo sọ pe ko si bi wọn ṣe maa sọ nipa itan idagbsoke ipinlẹ Ogun, ti wọn ko nii darukọ Oloogbe Ọladipọ Diya.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI