Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara ti ba gbogbo awọn ẹlẹsin musulumi jakejado agbaye, paapaa nipinlẹ naa yọ lori bi aawẹ ọlọdọọdun Ramadaani ṣe wọle wẹrẹ.
Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ yii ni Gomina AbdulRazaq ki gbogbo awọn musulumi ku amojuba aawẹ naa ti 1444 A.H., to si gbadura pe ẹmi to bẹrẹ rẹ ni yoo pari ẹ layọ.
Bakan naa lo b'awọn agba musulumi niluu Ilọrin, paapaa Ẹmir tiluu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari yọ lori idagbasoke ti ẹmi naa to de ba wọn.
O ni k'awọn eeyan lo anfaani asiko aawẹ yii lati maa ṣe aanu f'awọn eeyan, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun, bẹẹ ni ki wọn rii daju pe wọn n dagba soke nipa ti ẹmi.
AbdulRazaq ni k'awọn eeyan tẹsiwaju nipa gbigbe ninu ẹmi ati iwapẹlẹ, ki wọn si maa gba alaafia laaye, eyi ti yoo mu idagbasoke ba eto aabo ni Naijiria, paapaa ni Kwara.
No comments:
Post a Comment