Oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba lorileede Naijiria lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun ti sọ pe oun ko gba esi ibo ti ajọ eleto idibo, iyẹn Independent National Electoral Commission, INEC kede wi pe o gbe alatako oun lati inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC wọle.
Aderinokun to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lo sọrọ naa ni kete ti ajọ INEC kede ẹni to jawe olubori ninu eto idibo to waye lopin ọsẹ to kọja.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Aderinokun, Ọgbẹni Taiye Taiwo gbe jade, eyi to fi ẹda rẹ ranṣẹ si AWIKONKO lo ti sọ pe awuruju pọ ninu esi ibo ti INEC kede lọjọ Aiku, Sannde.
O ni ibo to kọja ohun ti awọn eeyan di lo pọ ninu eyi ti INEC kede rẹ jade fawọn araalu, to si ni abajade esi ibo naa kii ṣe eyi to tẹ araalu lọrun.
Siwaju sii lo sọ pe ibudo idibo to le ni ọgọrun kan ni wọn ti dibo kọja awọn to fi orukọ silẹ lati dibo.
O ni lati ibudo idibo ni awuruju ọhun ti bẹrẹ, to fi de awọn wọọdu to wa kaakiri ijọba ibilẹ mẹfa toun fẹẹ lọ ṣoju.
"Wọn ti ja awọn ara aarin gbungbun ipinlẹ Ogun lole. Ilana ọhun ti ja awọn eeyan kulẹ, ati pe nipa atilẹyin Oloye Olumide Aderinokun, pẹlu iranlọwọ mọlẹbi PDP nipinlẹ Ogun, a ko ni le gba esi ibo naa wọle.
"A maa tako esi ibo ọhun nitori pe kii ṣe ohun ti awọn eeyan n fẹ niyẹn. Oríṣiríṣi àpẹẹrẹ lo wa nilẹ, eyi ti a ri pe apọju ibo wa nibẹ, ti ẹrọ igbalode BVAS ko si ṣiṣẹ daadaa nipa gbigbe esi ibo sibẹ.
"Wọn ṣe awuruju ninu eto ati ilana naa ni, a ko si nii kawọ gbera lati jẹ ki ki wọn yan wa jẹ. A n lọ si ile ẹjọ Tribuna, a si fẹ ki awọn eeyan wa ni ikiyesara, ki wọn si yago fun iwa to lw da wahala silẹ."
Ọjọ Aiku, Sannde ni ajọ INEC kede Shuiab Salisu ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori pẹlu ibo 96,769, ti Aderinokun si ni ibo 52,940.
No comments:
Post a Comment