Bo ti ṣe pe ọjọ mẹwaa gbako ti ile ẹjọ agba orileede yii, Supreme Court paṣẹ pe ki awọn ọmọ Naijiria tẹsiwaju lati maa na owo naira ti tẹlẹ, ẹẹdẹgbẹta ati ọgọrun kan naira titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila ọdun 2023, Gomina Godwin Emefiele ti ile ile ifowopamọ agba, CBN naa ti wa sọrọ sita wi pe oun ti gba aṣẹ ile ẹjọ.
O ni ki gbogbo awọn ile ifowopamọ orileede yii patapata tẹle aṣẹ ile ẹjọ lai fi akoko ṣofo, ki wọn si maa gba awọn owo naa pada.
Emefiele ṣo pe lẹyin ipade toun ṣe pẹlu awọn alakoso ile ifowopamọ kaakiri orileede yii, eyi to ṣe lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii, loun ti paṣẹ fun wọn.
Ọrọ ti Emefiele sọ yii lo f'opin si gbogbo ibẹrubojo to ti wa lọkan awọn ọmọ Naijiria nipa isọro ti wọn n koju lori owo naa
Alakoso fidihẹ lẹka ikansira-ẹni, Isa AbdulMumin, tun fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade to pe akori rẹ ni ‘Owo N200, N500, ati N1,000 jẹ ojulowo owo ti awọn eeyan yoo maa na – CBN’.
No comments:
Post a Comment