Ẹgbẹ sọrọsọrọ lorileede Naijiria, Freelance and Independent Broadcasters Association of Nigeria (FIBAN), ẹka t'ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ṣetan lati ṣatilẹyin ibo fun gomina ipinlẹ naa AbdulRahman AbdulRazaq lati pada s'ipo lẹẹkeji, nitori awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ti wọn lo ti ṣe.
Wọn ni Gomina AbdulRazaq ti jẹ k'awọn mọ pataki iṣejọba awaarawa nipa awọon ohun to ti ṣe fun wọn kaakiri gbogbo ilu ati igberiko to wa n'ipinlẹ naa.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni awọn adari naa sọrọ yii lakoko ti wọn n ṣabẹwo si akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye ni ọfiisi rẹ to wa niluu Ilọrin.
Nigba to n sọrọ, alaga fidihẹ ẹgbẹ naa, Arabinrin Ramat Lawal jẹ ko di mimọ pe AbdulRazaq ti jẹ ki ipinlẹ naa di eyi to n mu nnkan rọrun fun oniruuru ọmọ ipinlẹ Kwara laaarin ọdun mẹrin din diẹ to ti wa n'ipo, eyi to sọ pe anfaani nla lo jẹ wi pe yoo gba ipo naa lẹẹkeji.
Alaga naa sọ pe ko sẹni meji t'awọn yoo dibo fun lakoko idibo to n bọ yii to kọja gomina wọn, ẹni to ni ifẹ araalu lọkan.
No comments:
Post a Comment