Ẹ wa wo ṣọọṣi ti wọn ti n ta ọmọ ikoko jẹun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 14, 2023

Ẹ wa wo ṣọọṣi ti wọn ti n ta ọmọ ikoko jẹun


Ileeṣẹ ọlọpaa orileede yii, ẹka t'ipinlẹ Imo ti ṣawari ile ijọsin ti wọn ti n ta awọn ọmọ ikoko danu lowo pọọku, koda ti ọwọ tun ti tẹ awọn olori ijọ naa.
 
Agbegbe kan ti wọn n pe ni School Garden, opopona MCC/Uratta, ijọba ibilẹ Owerri North, ipinlẹ Imo la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ti waye.
 
Ile ijọsin naa ni wọn pe ni Jesus Life Assembly.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ọmọbinrin, ọmọ ọdun mejidinlogun kan, Amarachi Okechukwu Dioku lo deede d'awati lọjọ kẹtalelogun, oṣu karun-un, ọdun 2021.

Lati ọjọ naa ni iroyin fi to wa leti pe wọn ko ri ọmọbinrin naa ti wọn lọmọ bibi Umudurualaoka, ijọba ibilẹ Mbaitoli ni, ko to di pe ẹnikan kofiri rẹ pẹlu oyun ninu, ti wọn si lọ ṣofofo f'awọn ọlọpaa.
 
Loju ẹsẹ ni wọn lawọn ọlọpaa ti lọ gbe olori ijọ naa, Ajihinrere Ugochi Orisakwe, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, pẹlu awọn ọmọ ẹyin ẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ buruku naa.
 
Awọn miran tọwọ tun tẹ ni Chidi Orisakwe, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn; Pauline Nwagbunwanne, ẹni ọdun mejilelogoji; Elizabeth Uzoma, ẹni ọdun mejilelọgọta, ati Chibueze Joy, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn.
 
Nigba ti wọn yoo fi ri Amarachi Dioku, oyun oṣu marun-un ti wa lara ẹ, to si jẹ kayeefi. Awọn ọlọpaa ni wọn gbe e lọ si ọsibitu fun itọju, ko to di pe wọn fa a le awọn obi rẹ lọwọ.
 
Ugochi, lakoko to n jẹwọ sọ pe oun ti wa lẹnu iṣẹ naa tipẹ. O ni tawọn ọmọbinrin naa ba ti bimọ inu wọn tan, awọn yoo wa ta awọn ọmọ tuntun naa f'awọn ọkọ atiyawo ti wọn n wa ọmọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI