Banki agba orileede Naijiria, Central Bank of Nigeria, CBN ti sọ pe awọn ile ifowopamọ ti wọn ba kọ lati ko owo atijọ jade sita yoo foju winna ofin awọn.
Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọsẹ yii ni CBN sọ pe oun yoo bẹrẹ sii ko awọnn owo atijọ ti wọn ti gba wọle f'awọn ile ifowopamọ si kaakiri Naijiria, lati le jẹ ki nnkan rọrun f'awọn araalu.
Lati ọdun to kọja l'awọn araalu ti n koju wahala ati iṣoro loriṣiriṣi latigba ti ijọba apapọ ati CBN ti kede owo naira tuntun, ṣugbọn ti ile ẹjọ agba ti pada paṣẹ wi pe k'awọn eeyan ṣi maa na owo atijọ lọ titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii.
Bi awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ninu eto ijọba orileede yii ṣe dide si wahala t'awọn eeyan n koju lori airi owo wọn gba l'awọn ile ifowopamọsi wọn, lo mu ki banki agba naa sọ pe ohun yoo bẹrẹ sii ko owo jade sita.
Siwaju sii ni wọn lawọn yoo bẹrẹ sii lọ kaakiri lati maa ṣọ awọn banki to ba kọ lati ko owo sita f'awọn araalu.
CBN sọ pe ki gbogbo awọn banki lọ si ẹka CBN to ba wa nipinlẹ wọn lat lọ maa gba awọn owo atijọ ọgọrun-un kan naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati igba naira, ki wọn si maa f'awọn onibara wọn lati na.
Ọjọru, ọsẹ yii ni gomina ile ifowopamọ agba, Godwin Emefiele ṣe ipade pẹlu awọn olori ile ifowopamọ kaakiri Naijiria, nibi to ti paṣẹ naa.
A gbọ pe latigba naa l'awọn ile ifowopamọ ti bẹrẹ sii gba awọn owo atijọ naa, lati maa f'awọn onibara wọn kaakiri orileede Naijiria.
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn alakoso banki lorileede yii ṣe ṣalaye, o l'awọn ti gba bẹrẹ sii gba owo atijọ naa lọwọ CBN, eyi ti yoo jẹ ki wọn le maa ko o sita pada f'awọn araalu.
No comments:
Post a Comment