Baagi ni Suliyat jigbe to fi dero kootu n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, March 31, 2023

Baagi ni Suliyat jigbe to fi dero kootu n'Ibadan


Pakopako ni iyaale ile ẹni ogoji ọdun kan, Suliyat Ganiyu n wo lonii, ọjọ Ẹti, Furaidee nigba ti wọn foju rẹ ba ile ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Iyaganku niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
 
Ẹsun ti wọn fi kan Suliyat, to mu ko foju bale ẹjọ ni ti baagi ti wọn sọ pe o jigbe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun 2023 ti a wa yii, iyẹn ni nnkan bi aago meji ọsan.

Agbegbe Itamaya ni wọn sọ pe Ganiyat ti ji baagi naa ti awọn nnkan bii kaadi ATM, kọkọrọ, ati ẹgbẹrun lọna aadọrin naira.
 
Nigba to n fẹsun kan niwaju Onidajọ T. B Oyekanmi, agbefọba, Sikiru Ibrahim sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Ganiyat tako iwe ofin ọdaran t'ipinlẹ Ọyọ, abala 390(9) t'ọdun 2000.
 
Ibrahim sọ pe obinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ọmọlade Adekọla lo ni baagi naa.
 
Onidajọ Oyekanmi nigba to n sọrọ sọ pe ki wọn gba beeli Ganiyat pẹlu onidaro meji tọọtọ ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira.
 
Bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI