Kayeefi nla gba a lọrọ iya arugbo kan, Iforiti Oloro si n jẹ f'awọn eeyan lori bo ṣe dana sun ọmọ rẹ, iyawo ọmọ rẹ ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ mọ inu ile ti wọn jọ n gbe, ti gbogbo wọn si dero ọrun alakeji.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni nnkan bi aago meji oru ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii ni iya agba naa dana sun awọn ọmọ ati awọn ọmọ rẹ naa mọle.
Ẹsun ti wọn ni mama naa fi kan wọn ni pe wọn ko tọju oun, ati pe wọn n fi ebi pa oun, idi ree toun fi dana sun wọn, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn.
Agbegbe kan ti wọn pe ni Apọnmu niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo niṣẹlẹ ọhun ti waye, ti a si gbọ pe awọn ara adugbo naa gbiyanju lati doola ẹmi awọn eeyan naa, ṣugbọn ti ẹpa ko pada boro.
Wọn ni asiko ti awọn eeyan ti sun ni mama ọhun ṣiṣẹ buruku naa.
Ọgbẹni Bayọ Adegboyega, ọkan lara awọn ara adugbo naa, nigba to n sọrọ sọ pe oju oorun loun wa toun fi n gbọ ariwo, ko to di pe oun taji lati jade sita.
Baale ile naa sọ pe loju ẹsẹ loun ti sare jade, lati ba wọn pa ina naa. O nigba tawọn maa fi wọle, nnkan ti bajẹ jinna kọja afẹnusọ.
O lawọn ko fi falẹ rara, ti wọn fi sare ko wọn lọ si ọsibitu ijọba ti jẹnẹra to wa niluu Akurẹ, ṣugbọn ti wọn ko gbawọn, ko to di pe wọn sare ko wọn lọ si ọsibitu FMC tiluu Ọwọ
Siwaju sii ni ọkunrin naa sọ pe o ṣeni laanu pe abigbẹyin wọn jade laye ni kete ti wọn de ọsibitu naa, ṣugbọn ti ọkọ atiyawo naa jade laye lalẹ ọjọ Aiku, Sannde.
O darukọ ọkọ atiyawo gẹgẹ bii Victor Oloro ati Rachael Oloro, to fi mọ awọn ọmọ wọn, Blessing pẹlu Toluwani.
Iya agba naa, nigba to n sọrọ, ṣalaye pe nitori ebi ti wọn fi n pa oun, lo jẹ koun pinnu lati dana sun wọn mọ inu ile.
Ṣugbọn agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa, Funmilayọ Ọdunlami Omisanya sọ pe oun ko tii gbọ nipa iṣẹlẹ naa daadaa, ṣugbọn toun yoo jẹ kawọn eeyan mọ bi nnkan ba ṣe n lọ.
No comments:
Post a Comment