Awọn to n fi orukọ ẹgbẹ wa lu jibiti lo fontẹ lu Dapọ Abiọdun fun saa keji - Ẹgbẹ oṣelu Labour pariwo faraye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, March 11, 2023

Awọn to n fi orukọ ẹgbẹ wa lu jibiti lo fontẹ lu Dapọ Abiọdun fun saa keji - Ẹgbẹ oṣelu Labour pariwo faraye

 
Ẹgbẹ oṣelu Labour n'ipinlẹ Ogun ti sọ pe iroyin to n kaakiri lori ayelujara wi pe ẹgbẹ naa ti fontẹ lu Dapọ Abiọdun lati pada s'ipo gomina lẹẹkeji kii ṣe otitọ, bi ko ṣe pe ayederu iroyin pọmbele ni.
 
Wọn ṣapejuwe ifontẹ lu naa gẹgẹ bi awuruju, ẹtanjẹ ati iṣini-lọkan, nitori pe ko si nnkan to jọ bẹẹ rara.
 
Awọn alakoso ẹgbẹ naa laipẹ yii ni wọn kede sita wi pe awọn ti fontẹ lu Dapọ Abiọdun lati dije du ipo naa lẹẹkeji, pẹlu ileri wi pe awọn yoo gbaruku ti ipolongo rẹ lati pada s'ipo naa lẹẹkeji, ati pe gbogbo ohun ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ba n fẹ, lawọn yoo ba wọn fẹ.
 
Ninu atẹjade ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Tokunbọ Peter gbe jade lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii lo ti sọ pe gbogbo awọn to lawọn fontẹ lu Dapọ Abiọdun ni wọn kii ṣe ojulowo ọmọ ẹgbẹ.
 
Peter ni awọn ti jawe lọ rọkunle fun wọn nitori awọn aṣemaṣe ti wọn ti ṣe.
 
O ni jibiti ni wọn fẹẹ lu awọn ọmọ ẹgbẹ alaimọkan, lati ro pe lotitọ ni ẹgbẹ Labour wa lẹyin APC, eyi to sọ pe ko bojumu rara, bi o ṣe iwa idaluru.
 
O tẹsiwaju pe Onimọ-ẹrọ Lookman Jagun to jẹ alaga igbimọ fidihẹ tẹlẹ, ati Michael Ashade lawọn ti le danu ninu ẹgbẹ naa tipẹtipẹ, ti ko si ṣẹyin awọn eeyan, nitori pe awọn gbe iroyin ọhun sita.
 
Siwaju sii lo sọ pe Michael Ashade atawọn ẹmẹwaa rẹ ni anfaani lati fontẹ lu oludije ti wọn ba n fẹ, ṣugbọn ki wọn yee lo orukọ ẹgbẹ Labour lati maa fi kede pe awọn fontẹ lu oludije kan lati ẹgbẹ miran.
 
Bẹẹ lo sọ pe iwa ọdaran pọmbele ni, ati pe ko yẹ ki ẹni to wa nipo agbara maa lọ ara rẹ pọ mọ awọn to n fi orukọ ẹgbẹ lu jibiti kaakiri nitori ohun ti wọn fẹẹ ri nidii oṣelu.
 
Lakotan, o ṣalaye pe awọn ni oludije s'ipo gomina, ti ajọ INEC si fọwọ si fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI