Ile ẹjọ agba orileede Naijiria lonii, ọjọ Ẹti, Furaidee ti paṣẹ pe ki awọn ọmọ Naijiria tẹsiwaju lati maa na awọn owo naira atijọ lọ titi di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2023.
Onidajọ Emmanuel Akomaye Agim lo gbe idajọ naa kalẹ, paṣẹ pe ki ile ifowopamọ agba, Central Bank of Nigeria ko owo atijọ ati tuntun sita f'awọn araalu lati maa na, titi di akoko naa.
Nigba to n sọrọ, O ni gbogbo aṣẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari pa lori owo naira tuntun ni ko ba ofin mu, o si tako ilana lilo ipo agbara.
No comments:
Post a Comment