Amugbalẹgbẹ agba pataki fun Saraki tun ba APC lọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 9, 2023

Amugbalẹgbẹ agba pataki fun Saraki tun ba APC lọ ni Kwara


Inu ironu nla ni Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orileede yii tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki wa bayii, pẹlu bi awọn ọmọlẹyin rẹ pataki-pataki ṣe n ba ẹgbẹ oṣelu miran lọ, to si tun jẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni wọn n ba lọ.
 
Ọnarebu Wasiu Bamidele, to jẹ amugbalẹgbẹẹ agba pataki fun Sẹnetọ Saraki, iyẹn Senior Legislative Aide ni wọn lo tun kede sita pe oun ti ba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lọ.

Bamidele ni wọn lo sọ pe oun ko le tẹsiwaju mọ ninu ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP), ati pe ilana ati eto iṣejọba APC tẹ oun lọrun.
 
Ọkunrin yii ni kansẹlọ ijọba ibilẹ Iṣin nigba kan ri, to si tun jẹ ọmọlẹyin pataki fun Saraki.

Bamidele kede sita lẹyin ipade to ṣe pẹlu Mutawalli tiluu Ilọrin, Ọmọwe Alimi AbdulRazaq ati amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori ọrọ oṣelu, Ọnarebu Moshood Alaka.
 
Nibẹ lo ti fi da wọn loju pe oun yoo rii daju pe oun ko gbogbo awọn ọmọlẹyin oun jade, lati dibo fun AbdulRazaq ninu eto idibo to n bọ yii
 
Ninu iroyin miran to tun fara pẹ ẹ, a gbọ pe ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu miran ni wọn ti fi atilẹyin wọn han si ẹgbẹ oṣelu APC, ti wọn lawọn si ti ṣetan lati ba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣiṣẹ papọ fun itẹsiwaju ipinlẹ Kwara.

Awọn ọmọ ati alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, SDP, YPP ati Accord n'ijọba ibilẹ Ekiti ni wọn ti sọ pe awọn ti ri ọjọ iwaju rere lẹgbẹ APC, ti wọn si lawọn yoo ṣiṣẹ fun ẹgbẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ darapọ mọ.
 
Lara awọon eeyan naa ni; 
 
• High Chief Adebayo

• Hon. Nathaniel Owolabi

• Elder David Ajayi (Ekiti LGA Chairman of YPP)

• Amb. Anjorin Babatunde (Founder, Bukola Saraki Ambassadors)

• Hon. Ileaje Segun aka Skoro (Former Councilor Osi Ward 1)

• Suleiman Olabisi Issah (Secretary, PDP Osi Ward 1)

• Raji Oladimeji Sikiru (Osi 2)

• Asanloko Olanrewaju (Osi 1)

• Aguntasoolo Emmanuel (Osi 2)

• Ashaolu Folly

• Dada Shina

• Kehinde Femi

• Lateef Tayo (Osi 1)

• Olowa Emmanuel (Ekiti LGA YPP Chairman)

• Olowa Basirat

• Ashaolu Ayo (Chairman, Ekiti LGA Accord Party)

• Oni Sunday (Cordinator, Ekiti Grassroot)

• Onipede Femi

• Baba Alodo

• Joseph Morenike

• Adewumi Lekan

• Ajayi Damilola (Osi 2)

• Raji Tajudeen (Osi 2)

• Abiodun Toyin (Osi 2)

• Kareem Rashidat


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI