A ko le ni eto idibo to yọranti labẹ iṣakoso Tinubu gẹgẹ bi aarẹ Naijiria - Rhodes-Vivour - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, March 22, 2023

A ko le ni eto idibo to yọranti labẹ iṣakoso Tinubu gẹgẹ bi aarẹ Naijiria - Rhodes-Vivour


Oludije s'ipo gomina ipinlẹ Ekoo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour, Gbadebo Rhodes-Vivour ti sọ pe kii ṣe eto idibo ti awọn eeyan n reti lo waye lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, ọdun 2023 ti a wa yii, bi ko ṣe iyanjẹ.

Gbadebọ sọ pe awọn yoo ja labẹ ofin lati rii pe ohun to tọ si wọn pada sọwọ wọn, ati pe ọna lati gbogun ti baba isalẹ loun fẹẹ yanju patapata.
 
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ wi pe eto idibo to yọranti ko le waye lorileede yii labẹ iṣakoso Tinubu gẹgẹ bi aarẹ Naijiria.
 
Gbadebọ lo sọrọ naa lonii, Ọjọru, Wẹsidee nibi ipade awọn akọroyin to pe lati fi erongba rẹ han lori eto idibo to waye lopin ọsẹ to kọja yii.
 
"Mo bẹrẹ lẹẹkan sii lati dupẹ lọwọ awọn ara Ekoo fun akitiyan wọn lati duro ipinnu ti wọn ni nipa ireti ati lai bẹru. Ọrọ wa jẹ eyi ti ibanikẹdun, ifẹ, iṣakoso rere to ṣoju-ṣaara.
 
"Ni ana, mo lo ọjọ mi lati ṣabẹwo si gbogbo awọn to farapa l'ọjọ Abamẹta, Satide nipa iwa idaluru ati wahala ni Abule-Ade, Surulere ati Ikẹja. Mo ṣalabapade awọn ọdọkunrin ati ọdọbinrin ti wọn fara gba ọta ibọn pẹlu ọgbẹ rẹpẹtẹ ni ara wọn.

"Mo jade si wọn lati jẹ ki wọn mọ pe mo wa pẹlu wọn, mo si mọ bi ọgbẹ wọn ṣe ri, mo si fẹ ki wọn mọ pe emi ati igbakeji gomina mi wa pẹlu wọn.

"A ti gbe ikanni kan dide ti a pe ni GRV CARES 2023, ki gbogbo ẹni to ba fara kaaṣa fi fọto wọn, owo ti wọn san l'ọsibitu ati esi ọlọpaa ranṣẹ, a si maa da gbogbo owo ti wọn na pada.

"Sẹnetọ Bọla Ahmẹd Tinubu pe fun imularada ni ana, ṣugbọn ko si imularada kankan lai si idajọ ododo. Ẹgbẹ oṣelu APC da wahala silẹ, wọn si gbogun ti awọn ara Ekoo, nipa ẹbọ riru ati ibọriṣa wọn."
 
Gbadebọ Rhodes-Vivour fi kun ọrọ rẹ pe awọn ko le maa tẹsiwaju ninu oṣelu agbero, tabi ijọba ologun ti yoo maa lo ipa ati ibọriṣa nipa sisọ ipinlẹ kan di ti ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo.

O ni wọn ko jẹ k'awọn eeyan ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bi ọmọ ilu lati Ikoyi si Ikẹja titi de Ikorodu ni wọn tẹ ẹtọ awọn mọlẹ.
 
"Wọn ko le fi awọn aṣeyọri wọn atẹyinwa polongo, ṣugbọn wọn le lo ọrọ ẹlẹyamẹya lati wọle."
 
Bakan naa lo tun sọ pe nitori ipinnu ẹnikan ṣoṣo ati ẹgbẹ okunkun rẹ, wọn fi ba iwa ọmọluabi ti ajọ INEC ti n ṣiṣẹ le lori lati bi ọdun mẹrin sẹyin jẹ. Ati pe nitori ipinnu ẹnikan, wọn sọ awọn ọba di irinṣẹ, nipa gbigbe oro jade lati fi ṣiṣẹ buruku ti Tinubu ati awọn ẹgbẹ okunkun rẹ yan laayo.
 
"Ko si eto idibo, iwa ipa ati jagidijagan loriṣiriṣi, ibọriṣa ojukoroju. Lori eyi la fi n gbin irugbin ohun rere ti yoo mu ohun to ṣẹlẹ nilẹ Rwanda waye.
 
"Ẹyin ara Ekoo, awọn ọta wa kii ṣe ara ile wa tabi awọn alejo abi awọn ara Ekoo to ni oriṣiriṣi ede. Ọta wa ni iwa ipa ati jagidijagan, aisi eto aabo, iṣẹ ati oṣi, iduro lojukan, iwa ajẹbanu, ati aini idagbasoke.
 
"Awọn eeyan kan naa yi ni wọn da gbogbo eyi silẹ. Wọn ti sọ iṣẹ ati oṣi di ohun ija agbara wọn, ati ọrọ ẹlẹyamẹya lati fi ṣi wa lọkan lori iwa ibọriṣa wọn. A ko le ni eto idibo to yọranti labẹ iṣakoso Tinubu gẹgẹ bi aarẹ.

"L'ọjọ Satide to kọja, a ri ọjọ iwaju Ekoo nipa oṣelu agbero, a si maa ja lọna to ba ofin mu lati rii pe a gba Ekoo wa pada."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI