Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti wọn yinbọn fun gbajagbaja agba oṣerebinrin nni, Peju Ogunmọla Ọmọbọlanle loko ere sinima kan ti wọn n ya lọwọ.
Fiimu agbelewo ti wọn ṣe ninu abule kan ti a ko mọ, ni wọn n ya lọwọ, to si ni ọfọ ninu.
Adewale Taofeek ti ọpọ awọn eeyan mọ si Digboluja lo yinbọn nibi to ti n pọfọ lọwọ pẹlu Ogunmọla lo yinbọn, ti ibọn naa si gba agba oṣerebinrin ọhun lọwọ.
Loju ẹsẹ lo ti pariwo sita wi pe oun ko le gba ki wọn maa doju ibọn kọ oun, nitori pe to ba lọ ṣeṣi yiwọ, ko sẹni ti yoo da sii.
O ni oludari ati alakoso ere naa ko ṣalaye foun tẹlẹ wi pe ọta ibọn wa ninu ibọn to wa lọwọ Digboluja, oun ko ba ti mọ boun yoo ṣe tete yẹ fun ibọn ọhun.
Loju ẹsẹ ni wọn ti bẹrẹ sii rawọ ẹbẹ sii, wi pe iru ẹ ko tun ṣẹlẹ mọ.
No comments:
Post a Comment