Ramọni Akanni ati ọmọ rẹ, Orindọla wọluu Brazil lati dabira - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 13, 2023

Ramọni Akanni ati ọmọ rẹ, Orindọla wọluu Brazil lati dabira


Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu idunnu ati ayọ nla ni gbogbo awọn ololufẹ agba olori nni, Alaaji Rahmọn Akanni ati ọmọ rẹ, Alaaja Alhaja Silifat Akanni Ebudọla Amọkẹ Orindọla, ẹni t'ọpọ awọn eeyan mọ si Ta L'Ọlọhun wa pẹlu bi wọn ṣe lọ fi orin da awọn ololufẹ wọn lara ya lorileede Brazil.
 
Ọsẹ to kọja yii la gbọ pe Alaaji Akanni, ẹni t'awọn eeyan tun n pe ni Arole K1 ati RK1 ati Alaaji Silifat lọ si orileede Brazil.
 
AWIKONKO gbọ pe Rua Barbosa, 42, Bela Vista So Sao Paulo lawọn mejeeji ti kọkọ lọ f'orin da awọn ololufẹ wọn laraya.
 
Siwaju sii la gbọ pe wọn yoo lo anfaani rẹ lati ṣe irin ajo afẹ, lati wo bi ilu naa ṣe ri.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI