Ọwọ tẹ 'Daddy GO' ati akẹkọọ ile ẹkọ bibeli pẹlu egboogi oloro ti wọn fẹẹ gbe lọ Dubai - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 12, 2023

Ọwọ tẹ 'Daddy GO' ati akẹkọọ ile ẹkọ bibeli pẹlu egboogi oloro ti wọn fẹẹ gbe lọ Dubai


Ẹwọ ajọ to n gbogun ti aṣilo oogun ati egboogi oloro lorileede Naijiria, National Drug Law Enforcement Agency, NDLEA ti tẹ gbajugbaja oludasilẹ ṣọọṣi kan niluu Eko ati awọn awọn akẹkọọ il ẹkọ bibeli rẹ pẹlu egboogi olori.
 
Papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa legbegbe Ikẹja niluu Eko lọwọ palaba wọn ti segi lọjọ Abamẹta, Satide to kọja, lakooko ti wọn fẹẹ ri irin ajo lọ sorileede United Arab Emirates, iyẹn Dubai.
 
Oludasilẹ ijọ Seraphic and Sabbath Assembly to wa niluu Eko, High Priest Nnodu Azuka Kenrick la gbọ pe akara rẹ tu s'epo pẹlu ikọ akọwọrin rẹ.
 

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ NDLEA, Fẹmi Babafẹmi fi sita lọjọ Aiku, Sannde, oni, o ni yatọ si olori ijọ tọwọ tẹ yii, ọwọ tun té awọn ọmọ ẹyin rẹ.
 
Udezuka Udoka to jẹ akẹkọọ ilẹ ẹkọ bibeli ti Emmanuel College of Theology to wa n'Ibadan; ati ẹnikan ti wọn pe ni ejẹnti, Oyoyo Mary Obasi, lọwọ palaba wọn segi papọ.
 
Egboogi oloro ti wọn pe ni Methamphetamine ati Skunk ti wọn ko sinu kẹẹgi omi nipasẹ ileeṣẹ akẹru NAHCO ni wọn ka mọ wọn lọwọ ni papakọ ofurufu naa l'Ekoo, lakoko ti wọn fẹẹ lọ Dubai.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Nnodu to jẹ oludasilẹ ijọ naa lọwọ tẹ ninu ṣọọṣi ẹ to wa ni ojule kinni, adugbo Sabbath to wa lagbegbe Ijeṣha, l'Ekoo.
 
Wọn  ni lẹyin ti ọwọ ti tẹ Obasi ati Udoka to ran niṣẹ de toru-toru ni wọn tu aṣiri sita wi pe oun lo ran wọn niṣẹ.
 

Skunk to to 283, ti ko din ni iwọn 14.90kiligiraamu ati 204giraamu egboogi 'meth' to wa ninu kẹẹgi epo lita marundinlọgbọn ni wọn gba lọwọ wọn ni papakọ ofurufu naa.
 
Obasi ni wọn lo darukọ oludasilẹ ijọ wọn, ati ọmọ rẹ, Chisom Obi, toun ti na papa bora ni wọn ran oun niṣẹ naa, pẹlu ileri owo nla ti wọn yoo fun un, to ba de.
 
O ni ko to di pe oun gbera ni wọn ti bura foun pe bi aṣiri ba tu, oun ko gbọdọ sọ fẹnikẹni, ati pe niṣe ni wọon dunkooko mọ ẹmi oun lati gbe egboogi naa, nitori toun ti mọ aṣiri wọn.
 
Babafẹmi wa jẹ ko di mimọ pe awọn tọwọ tẹ naa yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin iwadii awọn.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI