Ọwọ tẹ babalawo, ati awọn mọkanlelogun to n digunjale l'Ẹdo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 22, 2023

Ọwọ tẹ babalawo, ati awọn mọkanlelogun to n digunjale l'Ẹdo


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ẹdo ti tẹ baba agbalagba, ẹni ọdun marunlelọgọta kan ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju iṣẹ Babalawo lọ, lori ẹsun idigunjale ati ẹgbẹ okunkun.

Babalawo naa ati awọn gendekunrin mọkanlelogun ni ọwọ palaba wọn segi, ti wọn si sọ pe iṣẹ adigunjale ati ẹgbẹ okunkun nikan ni wọn fi n jẹun.
 
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa, Chidi Nwabuzor, nigba to n sọrọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee niluu Benin ṣalaye pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun yii lọwọ tẹ awọn eeyan naa.
 
Wọn ni iwadii nipa awọn kan ko ibọn sile lọna aitọ lawọn ọlọpaa ṣe, ko to di pe aṣiri babalawo naa tu pẹlu awọn isọngbe ẹ, to si jẹ pe wọn ba ibọn 'pump-action' kan lọwọ wọn.
 
Alukoro ọlọpaa naa ni mọto bọginni Mercedes GLK ati Lexus SUV ni wọn n gbe kaakiri lati fi digunjale ki aṣiri wọn too tu.
 
O lawọn afurasi ọdaran naa ti jẹwọ pe awọno ilu bii Benin ati Auchi lawọn ti n digunjale.
 
Bakan naa lo tun sọ pe mẹtala ninu awọn tọwọ tẹ yii ni wọn da wahala silẹ lori owo naira tuntun, ti awọn marun-un si jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun to n lo ibọn.
 
O lawọn yoo foju gbogbo wọn ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI