Ẹgbẹ awọn asẹwo niluu Abuja ti pariwo sita wi pe iṣẹ awọn ko lọ deedeemọ nitori owo naira to di ohun ti ko ṣee ri soju mọ, ti awọn banki naa ko si ko silẹ.
Awọn aṣẹwo naa ti wọn ba awọn akọroyin sọrọ laipẹ yii sọ pe pupọ awọn onibara wọn, ni wọn ti sun sẹyin, ti wọn ko si ri ti wọn ro mọ lasiko, eyi ti ko jẹ ki wọn ri owo mọ.
Ọjọ Aje, Sannde, ana lawọn aṣẹwo yii sọrọ naa niluu Abuja to jẹ olu-ilu Naijiria.
Wọn ni bo tilẹ jẹ pe igbesẹ to dara ni ọrọ owo tuntun ti ijọba gbe jade, pẹlu ilana owo nina, sibẹ wọn sọ pe ipenija aisi owo nita ti fa ijakulẹ fun ọrọ aje awọn.
Ọkan lara awọn aṣẹwo to sọrọ sọ pe 'No Cash' lawọn onibara wọn n pariwo kaakiri, ati pe bi awọn ba tun sọ pe ki wọn fi owo ranṣẹ, ṣe ni wọn yoo sọ pe nẹtiwọọki ko dara.
O ni ipenija nla lo jẹ fun wọn, nitori pe ọrọ aje awọn ti n dẹnukọlẹ patapata, pẹlu awọn onibara ko ṣe wa mọ.
No comments:
Post a Comment