Owo Naira tuntun: Buhari fẹẹ bawọn agbaagba Naijiria ṣepade pajawiri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 9, 2023

Owo Naira tuntun: Buhari fẹẹ bawọn agbaagba Naijiria ṣepade pajawiri


Aarẹ Muhammadu Buhari ti pe ipade awọn agbaagba ati alẹnulọrọ lorileede yii, eyi ti a mọ si State Council Meeting siluu Abuja.
 
Ọjọ Ẹti, Furaidee ni Aarẹ Buhari pe ipade naa si nile agbara, Aso Rock.
 
Ipade naa la gbọ pe o da lori bi etoo idibo apapọ orileede yii ṣe fẹẹ waye, ati lati f'opin si gbogbo rogbodiyan to n ṣẹlẹ lori ọrọ ọwọngogo epo rọbii ati owo naira.
 
Lara awọn ti yoo wa nibi eto ipade naa ni Aarẹ Buhari; igbakeji rẹ, Yẹmi Ọṣinbajo; akọwe ijọba, Boss Mustapha; awọn aarẹ ati olori orileede tẹlẹ; awọn adajọ agba tẹlẹ; aarẹ ile igbimọ aṣofin, Ahmad Lawan; Abẹnugọn ile igbimọ aṣofin kekere, Fẹmi Gbajabiamila; awọn gomina pata lorileede yii, to fi mọ adajọ agba, Abubakar Malami (SAN).

Nibi ipade ọhun la gbọ pe gomina banki apapaọ, Godwin Emefiele yoo ti sọ ibi ti ọrọ de duro lori owo tuntun ati ilana.
 
Aago mẹwaa aarọ ni ipade ọhun yoo bẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI