Ọwọ Amọtẹkun tẹ Ayọ ati Ṣarafa ti wọn ji batiri mọto meji gbe l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

Saturday, February 4, 2023

demo-image

Ọwọ Amọtẹkun tẹ Ayọ ati Ṣarafa ti wọn ji batiri mọto meji gbe l'Ọṣun

Collage-Maker-02-Feb-2023-08.09-AM-1536x1025.jpg

Ọwọ ileeṣẹ eto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka t'ipinlẹ Ọṣun ti tẹ gendekunrin meji kan lori ẹsun wi pe wọn ji batiri mọto meji ọtọọtọ gbe.
 
Ilu kan ti wọn n pe ni Igbaye, eyi to wa n'ijọba ibilẹ Odo-Otin la gbọ pe ọwọ ti tẹ awọn mejeeji ti wọn pe orukọ wọn ni Ayọ Ọmọtọṣhọ, ẹni ọdun mẹrindinlogun ati Ṣarafadeen Ayọ, ẹni ọdun mejilelogun.
 
Awọn mejeeji ni iroyin fi to wa leti wọn ti n da alaafia agbegbe naa laamu tipẹtipẹ, ko to di pe ọwọ palaba wọn segi.
 
Ẹnikan la gbọ pe o gbe mọto rẹ siwaju ile, ibẹ si ni lawọn mejeeji ti lọ ja ilẹkun mọto naa, ti wọn si ko awọn batiri to wa ninu ẹ salọ.
 
Wọn ni b'ẹni naa ṣe mọ, lo ti gba ileeṣẹ Amọtẹkun lọ lati fi to wọn leti, eyi to mu k'awọn Amọtẹkun naa bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn loju ẹsẹ, ti ọwọ si tẹ wọn.
 
Ọga agba Amọtẹkun, Ọgagun Bashir Adewinmbi nigba to n gbe iroyin naa sita ṣalaye pe ọjọ Aje, Mọnde to kọja lawọn mejeeji lọ jale ọhun, ṣugbọn ti wọn fi to wọn leti lọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
 
Bẹẹ lo sọ pe awọn mejeeji ti jẹwọ pe lotitọ lawọn jale naa, ati pe iṣẹ eṣu ni. Sibẹ o lawọn ti lọ fa wọn le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju iṣẹ iwadii wọn, ki wọn le foju wọn ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *