Ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro ilẹ̀ Nàìjíríà rèé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 3, 2023

Ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro ilẹ̀ Nàìjíríà rèé


Bí a bá ní kí a máa kà á ní ení-èjì-ẹ̀ta, a óò rí i gbangba pé, iye àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà tí wọ́n wà ní Òkè-Òkun kì í ṣe kékeré. Bí kò bá tilẹ̀ fẹ́ jọ àsọrégèé létí ìgbọ́ wa, mo lè sọ pé, àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà tó wà ní Òkè-Òkun ju iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n wà ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbí. Kò dín ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn, tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà ti ń sá kúrò ní Nàìjíríà lọ sí Òkè-Òkun.

Bí a bá ní kí a fi ojú ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn àti àwọn èyí tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ní Nàìjíríà wò ó, òjò ti ń pa igún ọmọ Nàìjíríà, ọjọ́ ti pẹ́. Yorùbá ní, ẹ̀yìnkùlé lọ̀tá wà, inú ilé ni aṣeni ń gbé. Kòkòrò tí ń jẹ ẹ̀fọ́ Nàìjíríà yìí, ara ẹ̀fọ́ Nàìjíríà gan-an ló wà. Àwọn Orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní Òkè-Òkun gan-an ni ọ̀tá fún gbogbo ilẹ̀ Adúláwọ̀, síbẹ̀, a kò fura.

Àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Nàìjíríà fi àṣírí ọrọ̀-ajé ilẹ̀ wọn pamọ́, wọ́n sì ń wádìí nípa ọrọ̀-ajé ilẹ̀ Nàìjíríà. Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti gbọ́ pé ohun rere kan fẹ́ wáyé ní Nàìjíríà, wọn yóò bẹ̀rẹ̀ ìwádìí nípa nǹkan náà, láti ṣe ìtakò fún àṣeyọrí rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Nàìjíríà ti fi ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ àti ìwé-ìrìnnà Òkè-Òkun ọ̀fẹ́ ta àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́rẹ láti kúrò ní Nàìjíríà tí wọ́n bí wọn sí. Bí a bá wo ṣààkun àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n fún ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ àti ìwé-ìrìnnà Òkè-Òkun ọ̀fẹ́ náà, ọlọ́pọlọ pípé, ọlọ́gbọ́n, olóye, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti akíkanjú ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ wọn.

Yorùbá ní, ọmọ tí a kò kọ́ nílé, ẹni ẹlẹ́ni ni yóò máa sìn. Ohun a ní là á náání, ni àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá wí, ṣùgbọ́n, àwọn àgbààgbà àti àwọn Adarí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò náání àwọn ọ̀dọ́ ọlọ́pọlọ pípé, ọlọ́gbọ́n, olóye, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti akíkanjú tí Ọlọ́run Ọba fi ta wọ́n lọ́rẹ láwùjọ wọn. Ṣé, ọmọ ẹni kò ní ṣe ìdí bẹ̀bẹ̀rẹ̀, kí a fi ìlẹ̀kẹ̀ sídìí ọmọ ẹlòmíràn ni àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá wí. Ojú olóko àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Nàìjíríà ni ilá wọn ṣe ń kó, tí ikàn wọn náà sì ń wẹ̀wù ẹ̀jẹ̀. Ojú àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Nàìjíríà ni àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Nàìjíríà ṣe ń kó gbogbo àwọn ọmọ wọn sá lọ sí Òkè-Òkun láti lọ fi wọ́n ṣe ẹrú títí di òní yìí.

Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní, ohun tí a bá fi sílẹ̀, ni ẹnu ewúrẹ́ ń tó. Ẹni tó rí ìfà ní ń jẹ ìfà ọ̀fẹ́, bí ẹni tí ó rí ẹsẹ̀ wèrè bù ṣoògùn ni ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Nàìjíríà jẹ́. Bí èyí bá wá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí àwọn àgbààgbà àti àwọn Adarí ilẹ̀ Nàìjíríà jí gìrì láti tọ́jú àwọn ọ̀dọ́ tí Èdùmàrè fi ta wọ́n lọ́rẹ, tí wọ́n jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé, ọlọ́gbọ́n, olóye, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti akíkanjú.

Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ sí ipò Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 2023 yìí múra tán láti:

1.) ṣe àtúnṣe sí abala ètò-ẹ̀kọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà yìí;

2.) máa fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé, ọlọ́gbọ́n, olóye, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti akíkanjú nínú ẹ̀kọ́ wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́;

3.) fi òpin sí ìdákúrekú ètò-ẹ̀kọ́, bí ìyanṣẹ́lódì àwọn Olùkọ́ àti ìfẹ́tọ́-dun-òṣìṣẹ́ Ìjọba;

4.) máa gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́gboyè sí iṣẹ́ Ìjọba; kí wọ́n sì tún 

5.) máa kíyè sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́gboyè àti àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé, ọlọ́gbọ́n, olóye, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti akíkanjú káàkiri Nàìjíríà, tí wọ́n ń ṣe àgbéjáde onírúurú ẹ̀bùn àtinúdá, ìmọ̀-ẹ̀rọ àti àwọn nǹkan mèremère mìíràn bẹ́ẹ̀.

Bí Ìjọba Àpapọ̀ bá pawọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ìjọba Ìpínlẹ̀ àti Ìjọba Ìbílẹ̀ Nàìjíríà, tí wọ́n ṣe àmójútó àwọn ọ̀dọ́ ọlọ́pọlọ pípé, ọlọ́gbọ́n, olóye, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti akíkanjú, tí wọ́n sì pèsè iṣẹ́ ìjọba fún wọn, ìṣòro Nàìjíríà yóò dé òpin. Àwọn ọlọ́pọlọ pípé, ọlọ́gbọ́n, olóye, onímọ̀-ìjìnlẹ̀ àti akíkanjú ọmọ Ilẹ̀ Nàìjíríà kò ní máa sá lọ sí Òkè-Òkun lọ ṣe ẹrú àwọn ọ̀tá Nàìjíríà mọ́.

Ìṣòro ilẹ̀ Nàìjíríà yóò sì dé òpin. 

Ẹ ṣeun oo.

Láìpẹ́, Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò tùbà tùṣẹ oo. Àmí.

... mo dákẹ́ díẹ̀ ná...

...mo sì fi ìyókù síkùn bí àwọn àgbààgbà...

Mo júbà oo
Ìbà Ọlọ́run Èdùmàrè
Ìbà Kábíèsí Ọlọ́tà Odò
Ìbà Ọkùnrin
Ìbà Obìnrin
Ìbà Ọmọdé
Ìbà ẹ̀yin àgbààgbà

Ẹ jẹ́ kó yẹ mí oo.


©
ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé Orí-Àrán lèmi ń jẹ́
Ẹ̀ṣọ́ Ọmọ Ọlọ́tà Odò
👏🙇‍♂️👏

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI