Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ọlatunji Peter lori ẹsun ipaniyan.
Yatọ si Ọlatunji tọwọ tẹ, ọwọ tun tẹ Akinlabi Akinbọwale, ẹni ọdun mejilelọgbọn; Taiwo Ọṣunwusi, ẹni ọdun mejilelogoji; Amos Oyewale, ẹni ọdun marundinlọgbọn ati Saiyan Umar toun jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaadọta.
Ẹsun ole jija, fifọ ile onile ni wọn fi kan wọn. Lara awọn nnkan ti wọn ji ni faanu oniduro, ṣokoto, bata, foonu at'awọn nnkan miran.
Siwaju sii lọwọ tun tẹ Adereti Solomon, ẹni ọdun mẹrindinlogoji; Ismaila Saliu, ati Ajadi Hammẹd lori ẹsun wi pe wọn ji kọmputa algbeeka, foonu, ẹrọ amunawa jẹnẹretọ, ati GOTV mẹjọ.
Bakan naa lọwọ tun tẹ Rabiu Yusuf, ọmọ ogun ọdun lori ẹsun idigunjale; Oluwaṣẹgun Ogungbẹsan ThankGod lori ẹsun ijinigbe ati jiji mọto 4Matic Mercedez Benz Jeep GL450 ti ko ni nọmba idanimọ.
Ahmed Yusuf, ẹni ọdun marundinlọgbọn; Azeez Mustapha, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọon ati Akintunde Eniọla Sukurat, ẹni ọdun mẹtalelogun lọwọ tẹ lori ẹsun idigunjale.
Nigba to n sọrọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe pupọ ninu wọn lawọn ṣi n ṣe iwadii lọwọ lori wọn, ati pe awọn yooku ni wọn yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ.
No comments:
Post a Comment