Oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar ti sọ pe oun yoo gba kamu ni, boun ko ba jawe olubori nibi eto idibo si ipo aarẹ lọdun 2023.
Atiku sọ pe oun kii ṣe ẹni akọkọ ti yoo kọkọ padanu ipo, bẹẹ loun ko nii jẹ ẹni igbẹyin ti yoo padanu ipo oṣelu lorileede yii ati lagbaye.
Nibi ifọrọwerọ ti Atiku Abubakar ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC Pidgin lo ti sọrọ naa jade, to si ni Ọlọrun lo n pin ipo fun ẹda, igbiyanju lasan ni ẹda n ṣe.
“Mi o kii ṣe ẹni akọkọ ti yoo padanu, bẹẹ ni mi o ni jẹ ẹni igbẹyin ti yoo padanu.”
Bakan naa lo tun sọrọ lori ẹsun iwa jibiti ati ajẹbanu ti wọn fi kan an, o loun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun, nitori pe ọpọ igba ni wọn ti wọdi oun, ti wọn ko ri nnkankan.
“Gbogbo ohun ti mo mọ ni pe, gbogbo ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan mi ni wọn ti ṣe iwadii ẹ lorileede yii ju ti ẹnikẹni lọ, ko si si nnkan ti wọn ri lodi si mi. Ko si nnkan tuntun ninu ọrọ naa mọ.”
No comments:
Post a Comment