O ti set! Ẹgbẹ akẹkọọ ipinlẹ Ogun l'awọn yoo ṣatilẹyin f'Aderinokun fun ipo aṣofin agba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 21, 2023

O ti set! Ẹgbẹ akẹkọọ ipinlẹ Ogun l'awọn yoo ṣatilẹyin f'Aderinokun fun ipo aṣofin agba


Bi iṣẹ kan to n bọ lọna ba ti pari, aṣa ti awọn eeyan maa n da lati fi jẹ ko ye awọn ti ko mọ ni pe 'O TI SET'. Eyi to tunmọ si pe gbogbo eto ti to tan.

Aṣa gan-an lo lọ ni ibamu pẹlu bi ẹgbẹ awọn akẹkọọ, ẹka ti ipinlẹ Ogun ṣe sọ pe awọn ti ṣetan lati gbaruku ti Olumide Aderinokun, ẹni to n dije du ipo aṣofin agba lati aarin gbungbun ipinlẹ naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ninu eto idibo to n bọ lopin ọsẹ ti a wa yii.

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa ni wọn fi ọkan Aderinokun, Akinruyiwa tiluu Owu Abẹokuta balẹ wi pe gbogbo ohun ti yoo ba gba l'awọn yoo fun un lati rii pe ọkunrin naa wọle gẹgẹ bi aṣofin ti yoo lọ ṣoju wọn l'Abuja lọdun 2023.

Ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii ni awọn akẹkọọ naa fi erongba wọn han, ti wọn si ni yoo dun mọ awọn ninu pupọ bi Aderinokun ba jawe olubori ninu eto idibo to n bọ yii.


Awọn alaṣẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ l'awọn ile ẹkọ giga mẹfa bii FUNAAB, MAPOLY, FCE OSIELE, DS ADEGBENRO, NOU ati Cooperative College to wa niluu Abẹokuta ni wọn panupọ sọ pe Aderinokun l'awọn to si lẹyin.

Yatọ si awọn wọnyi, awọn yooku l'awọn aṣoju ẹgbẹ akẹkọọ bii NANS, NAUS, NAPS ati NAOSS ni wọn l'awọn ti ṣetan lati b'awọn eeyan sọrọ lati dibo fun Aderinokun, nitori pe oun nikan l'awọn rii wi pe o kaju oṣuwọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI