O ma ṣe o! Fọlakunmi, ọmọ ọdun mẹẹdogun naa tun d'awati l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 2, 2023

O ma ṣe o! Fọlakunmi, ọmọ ọdun mẹẹdogun naa tun d'awati l'Ogun


Lati irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹtadinlọgbọn,oṣu kinni, ọdun 2023 ni wọn sọ pe wọn ti n wa ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹẹdogun yii, Ilyas Paradise Fọlakunmi, ti wọn ko si tii ri titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

Agbegbe Mowe to wa lopopona marosẹ Eko si Ibadan, ipinlẹ Ogun ni wọn sọ pe Fọlakunmi ti dawati, ti wọn ko si tii gburo rẹ sibikibi.
 
Kilaasi kan ti wọn pe ni ATS, iyẹn Accounting Technician Scheme ni wọno sọ pe ọmọ naa n lọ lagbegbe Mowe.
 
Inu adura ati aawẹ la gbọ pe awọn obi ati ọrẹ rẹ wa latigba naa, lori ki wọn le rii.
 
Wọn ti wa fi awọn ẹrọ ibanisọrọ meji kan sita fun ẹnikẹni to ba kofiri rẹ lati pe. Awọn ẹrọ ibanisọrọ naa ni 08121271751, 08030440407.

Bakan naa lẹ tun le ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo nibikibi ti ẹ ba ti kofiri ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI