Nnkan tun daru fun PDP ni Kwara: Awọn agbaagba kọwe f'ẹgbẹ silẹ lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 1, 2023

Nnkan tun daru fun PDP ni Kwara: Awọn agbaagba kọwe f'ẹgbẹ silẹ lojiji


Nnkan tun ti daru fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), nipinlẹ Kwara, pẹlu bi awọn agbaagba ninu ẹgbẹ oṣelu naa ṣe binu kọwe fẹgbẹ silẹ lojiji.
 
Gbogbo awọn agbaagba ati alẹnulọrọ ti wọn n woju wọn fun iranlọwọ ati ipa to jọju ninu eto idibo apapọ to n bọ lọna loṣu keji, ọdun ti a wa yii ni wọn kọwe wi pe awọn ko ṣe ẹgbẹ naa mọ.

Awọn agbaagba ati alẹnulọrọ mọkanla ni wọọdun Ibagun, ijọba ibilẹ Ilọrin East ni wọn sọ pe ko si ipinnu wi pe awọn tun ṣi n pada bọ lẹgbẹ naa.
 
Lara awọn to kọwe fẹgbẹ silẹ ni; A A Ẹlẹṣinmeji, alaga igbimọ alẹnulọrọ Ibagun tẹlẹ; Ismailia Kowa, ẹni to jẹ LOHE tẹlẹ fun gomina ana, Abdulfatai Ahmẹd; Alaaji Ayinla Wasiu, olori ọdọ Ibagun tẹlẹ; Mallam Dauda Abolaji; Mallam Ọlaide Ọladele, olori ọdọ Ibagun.
 
Awọn yooku ni Mallam Yunus Ibrahim, Mallam AbdulGaniyu Ayuba, Mallam Lukman Abiodun, Musa Ajibola, Bibire Abdullateef, ati Babs Igbaja.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI