Ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Ondo, eyi to wa niluu Akurẹ ti ju ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Sunday Oluwafẹmi sẹwọn gbere lori ẹsun wi pe o fipa ja ibale ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹsan.
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2019 ni iroyin fi to wa leti pe Sunday ti fipa ba ọmọ naa, to jẹ aburo iyawo ẹ laṣepọ karakara, ko to di pe aṣiri rẹ tu sita.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Yẹmi Fasanmi sọ pe awọn ẹri toun ri gba lori ẹsun naa kọja ohun ti wọn le da ọwọ bo, tabi gboju fo da.
O ni ẹsun naa tako abala kọkanlelọgbọn, idi kinni Section 31 (1), ofin ọmọde t'ọdun 2012, bẹẹ lo tun tako abala 218 ati 257 ti ofin ọdaran ipinlẹ naa, tọdun 2006.
No comments:
Post a Comment