Nitori foonu, Godwin lu ọga rẹ pa, lo ba ju oku rẹ si kọnga l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 3, 2023

Nitori foonu, Godwin lu ọga rẹ pa, lo ba ju oku rẹ si kọnga l'Ondo


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ ọmọ ogun ọdun kan, Josiah Godwin to kọ iṣẹ lọwọ, ẹni ti wọn lo lu ọga rẹ, Saviour Joseph pa, to si tun lọ ju oku rẹ danu sinu kọnga.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Imafon niluu Akurẹ n'iṣẹlẹ ọhun ti waye laipẹ yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa Funmilayọ Ọdunlami ṣe sọ, wọn ni wahala kekere kan lo ṣẹlẹ laaarin Godwin ati ọga ẹ, Odey Ogbaji, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Ibi ti wọn ti n fa wahala naa la gbọ pe Odey ti mu foonu Godwin, to si fọ ọ mọlẹ, eyi ti wọn lo bi ọmọkunrin naa ninu to fi ṣeku pa a.
 
Ọkan lara awọn aburo Odey ninu ọrọ rẹ, o ni
“L'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, aburo mi pe mi laaarọ, emi pẹlu ẹ ṣi sọrọ. Ṣugbọn l'Ọjọru, Wẹsidee mo gbiyanju lati pe e, ṣugbọn  ko lọ. Mo ro pe foonu ẹ ku ni, afigba to si ọjọ Satide, Abamẹta ti aburo mi pe mi wi pe oun ko ri Odey, bẹẹ loun ko rii pe.
 
“Nigba to ya, a pe ọmọṣẹ rẹ, wọn si beere ibi ti ọga rẹ wa, ṣugbọn ohun to sọ ni pe awọn jọ ni gbolohun asọ laaarin oru, o si fọ foonu oun mọlẹ ko to di pe o tun bẹrẹ sii lu oun, lẹyin eyi lo sọ pe ọga oun sọ pe koun lọ sun.
 
“O ni laarọ ọjọ keji, oun pinnu lati fi ibi tawọn ti n ṣiṣẹ silẹ. A tun wa beere lọwọ ẹ pe bawo lo ṣe maa ji laaarọ ọjọ keji, ti ko si nii ri ọga ẹ ko to maa lọ. O loun ro pe ọga oun ti lọ yagbẹ ni
 
“Igba ti a maa yẹ foonu ẹ wo, ko si nnkan to ṣe foonu naa, ko jọ wi pe wọn la foonu naa mọlẹ rara. Eyi lo jẹ ka fura sii.”
 
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Funmilayọ Ọdunlami, nigba to n sọrọ sọ pe otitọ ni, ati pe ọwọ ti tẹ ọmọkunrin naa, o si ti wa lahamọ awọn nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo.
 
O nigba tawọn ṣe iwadii ẹ lo jẹwọ pe inu kọnga ile ti wọn ti n ṣiṣẹ loun ju oku ọga oun si, lẹyin toun pa a tan.
 
“Ọmọ naa binu, o si lu ọga rẹ pa, o tun ju oku ẹ sinu kọnga. Ẹjọ naa ti wa ni ẹka ileeṣẹ wa to n ri si ẹsun ọran. O maa foju ba ile ẹjọ laipẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI