NECO: Ọga ile-ẹkọ to ba gba owo kọja ilana ijọba yoo foju winna ofin - Ijọba Kwara pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 13, 2023

NECO: Ọga ile-ẹkọ to ba gba owo kọja ilana ijọba yoo foju winna ofin - Ijọba Kwara pariwo sita


Ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn ọga ile ẹkọ girama kaakiri ipinlẹ naa, lati ma ṣe gba owo kọja iye ti ijọba la kalẹ fun owo iforukọsilẹ fun idanwo NECO, iyẹn National Examination Council (NECO).

Wọn ni iye owo ti ijọba la kalẹ ni ki gbogbo awọn ọga ile ẹkọ gba lọwọ awọn akẹkọọ ti wọn fẹẹ kopa ninu idanwo NECO naa.

Ijọba Kwara lo sọrọ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ nipinlẹ naa, Peter Amọgbọnjaye fi sita.

O ni ọga oun, Hajia Saadatu Madibo Kawu to jẹ Kọmiṣanna f'ọrọ eto ẹkọ lo paṣẹ naa, wi pe ẹni ti ọwọ ba tẹ lori ẹsun wi pe o gba owo kọja nnkan ti ijọba fi lelẹ yoo jẹ iyan rẹ n'iṣu.

Kawu ni lara awọn igbesẹ lati dẹkun iwa ajẹbanu ati ilọnilọwọgba to maa n ṣẹlẹ ni gbogbo asiko yii ni lati pariwo sita.

Amọgbọnjaye sọ pe ile ẹkọ girama ti St. Anthony to wa niluu Ilọrin, nibi ti wọn ti fi eto iforukọsilẹ naa lelẹ, ni ọga oun ti sọrọ naa jade, nibi to ti yanna-naa bi awọn akẹkọọ yoo ṣe san owo, ati iye ti wọn yoo san.
 
Owo fọọmu: ₦17,800.00
E-Regisration Charge: ₦1,050.00
Administrative Charge to School: ₦1,100.00
Four-Figure Table: ₦500.00
 
O ni apapọ iye owo ti ọmọ kan yoo san fun fọọmu naa jẹ ₦22,450 pere. Ati pe jke ẹkọ kọọkan yoo san ẹgbẹrun marunlenigba (₦5,200) gẹgẹ bi owo 'Photo Album, Syllabus ati Water Proof Certificate Folder/Jacket.'

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI