Mọto tẹ iyaale ile pa n'Ifọ lakoko to fẹẹ sọda - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 12, 2023

Mọto tẹ iyaale ile pa n'Ifọ lakoko to fẹẹ sọda


Mọto ayọkẹlẹ kan ti ko tii sẹni to mọ la gbọ pe o ti gba iyaale ile kan danu, to si pa a loju ẹsẹ.

Ọsan oni, ọjọ Aiku, Sannde la gbọ pe mọto tẹ obinrin naa pa lakoko to fẹẹ sọda si odikeji opopona.

Itosi teṣan ọlọpaa Ifọ lopopona Eko si Abẹokuta ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Awọn oṣiṣẹ aabo oju popona nipinlẹ Ogun, TRACE la gbọ pe wọn gbe oku obinrin naa lọ mọṣuari ọsibitu jẹnẹra ti Ifọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI