Mo ri agbara ojo to n gbe awọn ọmọde ati ọpọ dukia lọ lorileede Naijiria - Wolii Egunleti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 21, 2023

Mo ri agbara ojo to n gbe awọn ọmọde ati ọpọ dukia lọ lorileede Naijiria - Wolii Egunleti


Wolii Egunleti Samson Adejare ti rọ awọn ọmọ orileede Naijiria lati maa kiyesara, ki wọn si ma ṣe dakẹ adura lori agbara ojo to ni yoo ṣe ijamba to pọ lọdun 2023.
 
Ninu atẹjade ti Wolii Egunleti gbe jade sori ikanni ayelujara abanidọrẹ, iyẹn Fesibuuku rẹ laipẹ yii, eyi to tun fi ranṣẹ S'AWIKONKO lo ti sọ pe Ọlọrun ti fi iran nla kan han oun, to si ni k'awọn eeyan ma ṣe dakẹ adura lati dẹkun rẹ.
 
Agba Wolii naa sọ pe oun la ala ibẹru, nibi ti ojo ti n rọ, toun si ri bi agbara ojo naa ṣe n gbe awọn ọmọde. O tun ni kii ṣe ọmọde nikan loun ri ti agbara ojo naa gbe lọ, o loun ri ile ati dukia rẹpẹtẹ ti wọn n ba omi lọ.
 
Wolii Egunleti tẹsiwaju pe oun beere itumọ ala naa lọwọ Ọlọrun, to si ni Ọlọrun jẹ ko di mimọ foun pe ọpọ dukia ni yoo ṣofo, ti awọn eeyan yoo si padanu ọmọ wọn sinu agbara ojo.
 
O wa rọ awọn eeyan lati ma ṣe gba awọn ọmọ wọn, paapaa awọn ọmọde laaye lati ṣere tabi wẹ ninu ojo. Bẹẹ lo sọ pe ki awọn obi ati alagbatọ ma ṣe gba awọn ọmọde laaye lati ṣere bi atẹgun lile ba n fẹ kaakiri, nitori pe o lewu pupọ.
 
Ikede Pataki! Ikede Pataki!! Ikede Pataki!!!

Ẹ dakun, ẹ fi ọrọ yii ranṣẹ si ọpọlọpọ eniyan lati le gba ẹmi won la.
 
Mo la ala abami kan mọju Sunday, eyi si ba mi lọkan jẹ gidi gan-an. Mo rii pe ojo ṣu, o si fẹ atẹgun lile to gbe ile ati ọpọlọpọ ọmọde lọ ninu agbara omi ati ẹkun-un rẹrẹ omi ninu odo ati kọta. Eyi pami lẹkun-un gidi gan-an.
 
Sọ fun awọn ọmọ rẹ, ki wọn ma ṣe ṣere ninu ojo tabi ninu atẹgun to lagbara. A o ni sọ ọmọ nu lagbara Ọlọrun. Amin.
 
A o ni ṣofo dukia wa ati gbogbo ile wa lagbara Ọlọrun. Amin 
Lati owo: Woli Ogunleti Samson Adejare

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI