Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti pariwo sita f'awọn alatilẹyin rẹ n'ipinlẹ Eko lati dawọ wahala duro, nitori pe kika esi idibo apapọ ṣi n tẹsiwaju.
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ẹgbẹ oṣelu Labour lo n lewaju ninu eto idibo to waye n'ipinlẹ Eko, koda, ti a gbọ pe ibudo ti Tinubu ti n dibo ni Ikẹja, ẹgbẹ oṣelu Labour lo jawe olubori nibẹ.
Tinubu sọ pe oun ṣetan lati gba kamu lori ibi ti idibo yii ba fi si, ati pe oun yoo gba ibi ti ibo naa ba foriṣanpọn si.
Esi idibo naa ti ẹgbẹ oṣelu APC fi lulẹ, lo mu k'awọn ọmọ ẹyin Tinubu fa ibinu yọ, ti wọn si fẹ maa da wahala silẹ kaakiri, nitori pe Obi lo jawe olubori.
Ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin f'ẹgbẹ oṣelu APC, Bayọ Ọnanuga gbe jade lonii, ọjọ Aje, Mọnde, Tinubu sọ pe ki onikalulu lọ so ewe agbejẹ m'ọwọ.
O ni esi idibo to waye l'Ekoo, ko yẹ ko jẹ oun ti wọn le tori rẹ fa wahala, nitori pe ohun to dara nipa eto iṣejọba awaarawa ni lati dibo fun oludije to ba wu wa lọkan.
“Nitori wi pe a padanu l'Ekoo ko sọ pe ki wahala ṣẹlẹ. Gẹgẹ bi oloṣelu, ẹnikan yoo padanu, bẹẹ si lẹnikan yoo bori. A ni lati maa tẹle ilana kaakiri orileede yii, ka si gba ifẹ ati alaafia laaye.”
No comments:
Post a Comment