Liṣabi: Alake fẹẹ da MacGregor, Olu Orile-Ilawọ ti wọn ṣẹṣẹ yan lọla l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 16, 2023

Liṣabi: Alake fẹẹ da MacGregor, Olu Orile-Ilawọ ti wọn ṣẹṣẹ yan lọla l'Abẹokuta


Gbogbo eto lo ti pari patapapta bayii fun Alakẹ ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmnu Gbadebọ lati fi ẹbun nla rabandẹ da ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bi Olu Orile-Ilawọ, Olunla Oluwaṣẹgun Alexander MacGregor lọla.

Lara eto alakalẹ ti wọn la kalẹ fun ti ayẹyẹ ọdun Liṣabi to bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni idalọla naa wa fun un.

Ọla tii ṣe Ọjọ Ẹti, Furaidee la gbọ pe eto idalọla naa fẹẹ waye, ni gbọngan ayẹyẹ ti OK Centre to wa ni Ibara GRA, Abẹokuta, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Aago meji ọsan ni eto naa yoo bẹrẹ pẹlu awọn alakalẹ loriṣiriṣi.
 
Kii ṣe pe wọn deede fẹẹ fi aami ẹyẹ da MacGregor lọla, bi ko ṣe pe wọn fẹẹ mọ riri awọn ipa to ti ko ninu idagbasoke ati ilọsiwaju ilu Ẹgba, ipinlẹ Ogun ati orileede Naijiria lapapọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI