Iya to n jẹ awọn ọmọ Naijiria kii ṣe ohun amuyangan rara - Ọmọtọla Jọlade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 1, 2023

Iya to n jẹ awọn ọmọ Naijiria kii ṣe ohun amuyangan rara - Ọmọtọla Jọlade


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Ọmọtọla Jọlade-Ẹkẹinde ti sọ pe iya to n jẹ awọn ọmọ orileede Naijiria kii ṣe ohun amuyangan rara, nitori pe ko tọ si wọn.

Ọmọtọla lo sọrọ naa laipẹ nigba to n ṣe agbeyẹwo igbe aye awọn oyinbo alawọ funfun si ti awọn eeyan dudu.

O ni ẹdun ọkan lo maa n jẹ foun ni gbogbo igba toun ba n ri bi awọn eeyan ṣe n jiṣẹ-jiya lorileede Naijiria.

Ilu-mọ-ọn-ka oṣerebinrin naa lo kuro lorileede Naijiria pẹlu idile rẹ lọdun meji sẹyin jẹ ko di mimọ pe iya to n jẹ awọn araalu kii ṣe ohun amuyangan rara.

“Awọn ọmọ Naijiria ja fafa ju ki wọn maa jiya lọ, ati pe iya naa ko yẹ ki jẹ ẹkọ ti wọn le maa fi ṣakọ kaakiri.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI