Ṣenetọ Orji Uzor Kalu ti pariwo sita wi pe iya to n jẹ oun lasiko yii ti n kọja nnkan toun kan le maa kawọ gbera, to si ni iṣoro toun n koju nitori owo naira ti ko see ri soju mọ ti fẹẹ de gongo ori ẹmi oun.
Kalu lo sọrọ yii lakoko to n dahun ibeere lori amohunmaworan ileeṣẹ Channel lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nibi to ti n sọrọ lori owo naira tuntun.
O ni ilana ati ofin owo naira ti ile ifowopamọ apapọ orileede Naijiria, iyẹn Central Bank of Nigeria, CBN gbe kalẹ ti n ṣakoba nla fun oun ati idile oun.
Kalu sọ pe igbesẹ ati ilana ti CBN gbe kalẹ lori ayipada owo Naijiria, ṣugbọn to sọ pe kii ṣe iru asiko bayii lo yẹ ki iru igbesẹ naa waye, ati pe ọna ti wọn gbe e gba ko tọ.
“Ẹ maa rii pe igbesẹ ati ilana naa dara, ṣugbọn nitori pe mi o kii ko owo sile. iya n jẹ mi gidigidigi.
“Laipẹ yii, alabojuto ile mi pe iyawo mi, o si sọ fun un pe a ko ni owo kankan lati fi da ina ounjẹ. Niṣe ni iyawo mi n sare kaakiri lati wa ọna abayọ, nitori pe awọn ti wọn n jẹun nile wa le ni igba.”
No comments:
Post a Comment