Ọjọ́ ńlá gbáà ni Ọjọ́ Kọkànlélógún, Oṣù Erèlé, Ọdún 2023 yìí jẹ́ nínú ìgbésí ayé ọ̀dọ́kùnrin òjìmì Akéwì-Akọ̀wé tó gbajúmọ̀ káàkiri ilẹ̀ Nàìjíríà, Ìṣọ̀lá Sauban Àlàdé Orí-Àrán pẹ̀lú bó ṣe gba oyè ọ̀mọ̀wé nínú èdè Yorùbá.
Ìdí ni pé, gbogbo akitiyan tí ó ṣe lórí ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti ipele Ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni-Àgbà tí ó ti gba Oyè N.C.E, ẹ̀kọ́ tí ó kọ́ láti gba Oyè Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀ Àkọ́kọ́ (B. A.), ẹ̀kọ́ mìíràn tí ó kọ́ gba Oyè Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀ Kejì (M. A.) àti èyí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí lónìí láti gba Oyè Ọ̀mọ̀wé (PhD), orí Àṣà, Èdè àti Lítíréṣọ̀ Yorùbá ni gbogbo ẹ̀ dá lé.
Ìrìn-àjò Akéwì-Akọ̀wé yìí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ nínú Ọgbà Ilé-Ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ti Ilé-Ifẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2010, nígbà tí ó jẹ àǹfààní ẹ̀bùn Ẹ̀kọ́-Ọ̀fẹ́ lọ́dọ̀ àwọn Ọba Àládé Ilẹ̀ Yewa-Àwórì nínú Ọdún 2009 fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ rẹ̀. Àwọn Ìgbìmọ̀ Yewa-Àwórì Royal Scholarship Boards lábẹ́ àkóso Ọba Samuel Ojúgbélẹ̀ Ọbásogun Kejì, Onílogbò Àwórì àti Ọba Àlàní Oyèdé, Ọlọ́tà ìlú Ọ̀tà Àwórì ni wọ́n fún ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé ní ẹ̀bùn Ẹ̀kọ́-Ọ̀fẹ́ náà láti ọdún 2009 tí ó fi bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀ Àkọ́kọ́ (B. A.) títí di ìgbà tí ó fi tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀ Kejì (M. A.) àti èyí tí ó fi kẹ́kọ̀ọ́ gboyè Ọ̀mọ̀wé (Ph.D) yìí.
ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé ti kọ́kọ́ lọ sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Tai Solarin University of Education, Ìjagun láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ Olùkọ́ni-Àgbà nínú Èdè Yorùbá àti Ìmọ̀-Ìtàn-Àwùjọ (Yor/Hist.). Ní kété tí ó sì parí ẹ̀kọ́ náà ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Olùkọ́ni ní A. U. D. Comprehensive High School, Láfénwá-Òtà, kí ó tó tún lọ sí Local Government Commercial School, Atan-Ọ̀tà láti ṣe iṣẹ́ Olùkọ́ni níbẹ̀ náà. Lẹ́yìn èyí ni ó di Olùkọ́ni ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Ajọgbó Grammar School, Ajíbọ́dẹ-Ọ̀tà. Ilé-Ẹ̀kọ́ Ajọgbó Grammar School tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ Olùkọ́ni nígbà náà, ni ó ti gba Ẹ̀bùn Ẹ̀kọ́-Ọ̀fẹ́ lọ́dọ̀ àwọn Yewa-Àwórì Royal Scholarship Board ní ọdún 2009, tí ó fi kọ̀wé fi iṣẹ́ Olùkọ́ni sílẹ̀ láti lè mú èròǹgbà rẹ̀ ṣẹ lórí kíkọ́ èdè Yorùbá dé ibi tí ó ní àpẹẹrẹ rere.
Èròǹgbà tí ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé ní lọ́dún náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ mú ṣẹ lónìí Ọjọ́kọkànlélógún Oṣù Erèlé, Ọdún 2023 yìí. Ohun tí ó fà á, tí inú ọkùnrin Akéwì-Akọ̀wé yìí fi dùn dé góńgó ọkàn-àyà rẹ̀ nìyí.
Ó rí i dájú pé, kò rọrùn láti gun àwọn àkàsọ̀ tí ó gùn ní àgùnlà yìí. Ìgbàgbọ́ Sauban Àlàdé Orí-Àrán ni pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n ń tiraka láti gba Oyè Ọ̀mọ̀wé yìí, tí kò sí àǹfààní fún wọn. Ìdí nìyí, tí Sauban Àlàdé Orí-Àrán fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Ọba Aláṣẹ tí ó fún un ní àǹfààní láti parí ẹ̀kọ́ yìí láyọ̀ àti àlàáfíà.
Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó tún dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run tí ó jẹ́ kí ó ṣe é ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àpilẹ̀kọ tí ó fi gba Oyè Ọ̀mọ̀wé tó sì jẹ́ kí ó parí rẹ̀ láyọ̀. Ó tún dúpẹ́ pé Ọlọ́run dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, Ó sì tún rán aláàánú sí i láti ṣe àṣeyọrí ẹ̀kọ́ yìí láyọ̀. Ó fi ẹ̀mí ìmoore hàn sí Ọlọ́run, lórí gbogbo àánú tí ó rí gbà.
Ó ní "Mo dúpẹ́ dúpẹ́, mo dú pẹ̀pẹ́ òkun lọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúṣọlá George ọmọ Ajíbadé tí ó jẹ́ alábòójúytó iṣẹ́ mi yìí.
Onípẹ̀ẹ́ Àjó
Ọmọ ọmọtárá
Ọmọ Oyèniràn,
Ọmọ yànmùyánmú Ìsàlẹ̀ Ọ̀fà
Yànmùyánmú Ìsàlẹ̀ Ọ̀fà tí ń ṣe fújà láìlápá
Wọn ò níí fikú ròyìn rẹ fún wa.
Iṣú ọmọ á jinná fún ọ jẹ.
Wà á fọwọ́ páwú
Wà á sì fèrìgì jobì láṣẹ Ọba Èdùmarè."
ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé "Àwọn Yorùbá sọ pé, ohun ẹni kì í di méjì, kí inú ó bíni. Ohun tèmi wá di púpọ̀ lọ́dọ̀ alábòójútó iṣẹ́ àpilẹ̀kọ tí mo fi gba Oyè Ọ̀mọ̀wé. Olùkọ́ mi ni, òun náà sì tún ni ó dúró bí olùbádámọ́ràn fún mi. Bákan náà ẹ̀wẹ̀, olùrànlọ́wọ́ ni ọ̀gá mi yìí tún jẹ́ fún mi lórí gbogbo ọ̀nà tí mò ń tọ̀ láti jẹ́ ènìyàn pàtàkì láwùjọ.
Bí ó ti ń ṣe sí àwọn ènìyàn, tí ayé wọn fi ń dára, ni ó ṣe fún èmi náà. Ó dájú pé, òkè lọwọ́ afúnni ń gbé, òkè lẹmu ń ru sí, òkè lọlá Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúṣọlá George ọmọ Ajíbadé yóò máa lọ. Wà á fi ọwọ́ páwú, wà á sì tún fi èrìgì jobì láṣẹ Ọba Èdùmarè. Iṣu ọmọ á jinná fún ọ jẹ. Àṣẹ."
Ó tún tẹ̀ síwájú nínú ọpẹ́ rẹ̀ pé òún dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn olùkọ́ òun àti àwọn òṣìṣẹ́ ní Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ Ìmọ̀-ẹ̀dá-èdè àti Àwọn Èdè Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní Ilé-ẹ̀kọ Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọwọ̀. Ó ní "Ọpẹ́ mi náà bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olórí-ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ wa, Ọ̀jọ̀gbọ́n Felix Abídèmí Fábùnmi, Ọ̀jọ̀gbọ́n Fẹ́mi Adéwọlé, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọ̀jọ̀gbọ́n Láídé aya Ṣhẹ́bà, Àrìnpé aya Adéjùmọ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Sàláwù Akeem Ṣẹ́gun, Ọ̀jọ̀gbọ́n Abíọ́dún Ògúnwálé, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Ọ̀pẹ́fèyítìmí, Ọ̀mọ̀wé Àdíjat aya Fálẹ́yẹ, Ọ̀mọ̀wé Kọ́lá Adéníyì, Ọ̀mọ̀wé Fẹ́mi Bámgbádé, Ọ̀mọ̀wé Waheed Jayéọlá, Olóògbé Ọ̀mọ̀wé Abídèmí Ọlájùmọ̀kẹ́ Àjùwọ̀n (kí Ọlọ́run fi ọ̀run kẹ́ ẹ), Ọ̀mọ̀wé Bùnmi aya Bernard, Arábìnrin Grace aya Adébáyọ̀, Alàgbà Akinọ̀ṣun àti gbogbo àwọn yòókù. Ẹ ṣeun."
Ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo mọ̀lẹ́bí Orí-Àrán; Olóyè Ìṣọ̀lá àti aya rẹ̀ (bàbá àti ìyá rẹ̀), Ọ̀gbẹ́ni Ìdòwú Ìṣọ̀lá, Mọ́ríámọ̀ Ìṣọ̀lá, Baseerah Ìṣọ̀lá, Àyúbà Ìṣọ̀lá, Àjímọ̀ Ìṣọ̀lá, Aishat Ìṣọ̀lá, Rihanot Ìṣọ̀lá, Khaleed Ìṣọ̀lá, Habibat Ìṣọ̀lá (Ibrahim), Adérónkẹ́ Ìṣọ̀lá, Kudirat Ìṣọ̀lá àti Faatihu Adéṣínà Ìṣọ̀lá (àgbà) Faatihu Olúṣínà Ìṣọ̀lá (kékeré), Àjọkẹ́ Nimotallahi Ọyátáyọ̀-Ìṣọ̀lá. Àwọn olùkọ́ rẹ̀ ní Ọ̀tà àti Ìjẹ̀bú: Àláájì Ọlátúnjí Isiaq Abdulahi Ajíjọlá-Ànọ́bì, Khaleefa Ọ̀ttún Ọládàpọ̀ Afọlábí Abdulfatai, Mr. Tẹjúmọ́lá, Mr. Ajíbọ́sẹ̀, Mrs. Ìdòwú, Mr. Ògúngbàyí, aya Olíyìdé, aya Abdullahi, Mr. Wahab Ibrahim Adégbayì àti Olúwatóyìn aya rẹ̀, Mrs. Sàlòmí, Ọ̀mọ̀wé Ọnànúgà C.O, Ọ̀mọ̀wé Adams Justina Ọlábọ̀, Mrs. Olóyèdé, Mr. Agboọlá, Mr. Akínnífẹ̀sí, Mr. Dágundúró, Ọ̀mọ̀wé Ayọ̀bámi Misturah aya Tábí-Àgòrò, àti Ọ̀mọ̀wé aya Bánjọ àti àwọn olùkọ́ mi ní YSAN: Ọ̀jọ̀gbọ́n Lérè Adéyẹmí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Dúró Adélékè, Ọ̀jọ̀gbọ́n Dọ̀tun Ògúndèjì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọlátẹ́jú Adéṣọlá, Ọ̀jọ̀gbọ́n Olúgbóyèga Àlàbá, Ọ̀jọ̀gbọ́n Adébọ̀wálé Yẹ́misí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Táíwò Olúnládé, Ọ̀jọ̀gbọ́n Caleb Ọládélé Orímóògùnjẹ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Àrìnpé Adéjùmọ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Abíọ́dún ÒNÍ, Ọ̀mọ̀wé aya Adágbádá àti Ọ̀mọ̀wé Lẹ́yẹ Adéyẹmọ, Ọ̀mọ̀wé Igbókọ̀yí Adéyẹmí àti aya rẹ̀.
Ọpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ gbogbo àwọn Orí-Adé ilẹ̀ Àwórì tí wọ́n fún mi ní ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ láti ọdún 2009 títí di ọdún 2023, Kábíèsí Ọba Samuel Ojúgbélẹ̀ Onílogbò ti ìlú Ìlogbò àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọba Abdu-Kabeer Ọbalánlẹ́gẹ́ Ọlọ́tà ti ìlú Ọ̀tà.
Ó sì tún kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀; Khaleefa Ọ̀ttún Ọládàpọ̀ (Afọlábí) Abdulfatai, Ọ̀ttún Ọláńrewájú, Ọ̀ttún Ọpẹ́yẹmí, Ọ̀ttún Ganniyat, Ọ̀ttún Rihanat Modúpẹ́, Akinòsì Ọládiméjì Adédèjì, Adémọ́lá Dáúdà (Prince), Ìdòwú Saheed Olúwaṣínà (Ààrẹ-Àgò), Olóyèdé Qudus (SNR), Ọdẹ́doyin Ọláwálé (Walex), Alfa Bashir, Abíọ́dún Fábọ̀dé (Bọ̀ọ̀lì), Mámòórá Olúwaṣégun, Fágbhùn Wasiu Abídèmí (Abu Faahim), Ridwanuah Adékúné (Abu Jafar) àti aya rẹ̀, Ọ̀gá mi Oyèyẹmí Kẹ́hìndé Olúbùnmi (ANTP Adó-Odò Ọ̀tà), àwọn olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ STMA, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Ajọgbó Grammar School, STMA, FCT College of Education Àbújá, FCE College of Education Òṣíẹ̀lẹ̀, FCE College of Education (SPED) Ọ̀yọ́, FCE College of Education, Ìwó; Tai Ṣólàrin University of Education JUPEB Ọ̀sọ̀sà, Mr. Akíndélé Isiaq àti aya rẹ̀, Fájìmí Fáníyì Adéyẹmí, Adélékè Sodiq, Adéwálé Adémúyìwá Lukman (Akéwì), Joseph Ọmọ́táyọ̀ Kọ́láwọlé, Ọyágbénjó Abíọ́dún Oyèsọjí àti Àjọkẹ́ aya rẹ̀, Fọlárìn Gbénga Davids (Ọ̀rọ̀dọrọ̀), Mr. Àjàyí, Àláájì Abíọ́dún Adédèjì Lámínà, Ibrahim Wahab Adégbayì àti aya rẹ̀ Olúwatóyìn.
Àwọn Ọ̀rẹ́ àti olólùfẹ́ mi bí:
1.) Ààrẹ Kẹ́hìndé Oṣùọlálé
2.)Bákàrè Taiwo Wahab
3.) Adépọ̀jù Adémọ́lá
4.) Olóyè Kudirat Dìísù
5.) Olóyè Tádé
6.)OMOOBA ADEMOLA OGUNGBAYI
7.) Adeyemi Azeezat Nifemi
8.) Ade-Elvis omotunde sussan
9.) Otaniyi Fatimat Jadesola
10.) Hon. Iregbemi Daniel
11.) Bar. Ayodele Samuel
12.)Sofela Tunrayo bola
13.)Damilare Abass Adewunmi
14.)Onifade Awotunde Olawale
15.)Adeniji Aderayo F
Ó tún sọ pé "Ibi ayọ̀ ni ìdúpẹ́ mi yìí yóò ti kádìí. Ọpẹ́ mi lọ sí ọ̀dọ̀ Ayọ̀ Ìjẹ̀bú-Òde, àǹtí mi, ọ̀rẹ́ mi, olùrànlọ́wọ́ mi, olùkọ́ mi, ọ̀gá mi, tí ó jẹ́ olùkọ́ ní Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ Èdè Yorùbá ní Tai Ṣólàrin University of Education, Ìjẹ̀bú-Òde. Ayọ̀bámi Misturah aya Ọlábọ̀dé àti Ibrahim Wahab Adégbayì olówó orí Olúwatóyìn. Ẹ ṣeun mi o. Ọpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹ̀yin olólùfẹ́, ọ̀rẹ́, akẹ́kọ̀ọ́, alájọgbépọ̀, olùrànlọ́wọ́, olùkọ́, mọ̀lẹ́bí àti gbogbo ẹ̀yin tí a jọ ń ṣe ẹgbẹ́ ANTP, FIBAN, ISOOF, YOSSAN, Akọ́mọlédè, YSAN ní Nàìjíríà àti Òkè-Òkun. Mo tún wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí ó yan àwọn mẹ́fà wọ̀nyí fún mi láyé: Bàbá àti Ìyá mi ní ìlú Ọ̀tà (Mọ̀lẹ́bí Ìṣọ̀lá Orí-Àrán), àwọn àlùfáà mi méjèèjì (Àláájì Ọlátúnjí Isiaq Abdulahi Ajíjọlá-Ànọ́bì àti Khaleefah OTTUN Abdulfatai Afọlábí Ọládàpọ̀ Ọlọ́huntóyìn Àdúà-ńgbà TMON.) pẹ̀lú gbogbo àwọn Olùrànlọ́wọ́ mi."
Ó ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Alákòóso Ilé-Iṣẹ́ Orí-Àrán Ventures, Àjọkẹ́ Nimottallahi Ọyátáyọ̀-Ìṣọ̀lá Orí-Àrán tí wọ́n bá òun tẹ iṣẹ́ àpilẹ̀kọ tí ó fi gba Oyè Ọ̀mọ̀wé yìí. Ó sì tún kí Káábíèsí Aláyélúwà Ọba Ojúgbélẹ̀ Samuel Olúfẹ́mi Ọlágoróyè Ọbáṣogu III (HRM) Onílogbò ti ìlú Ìlogbò Àṣòwó tí wọ́n darí àwọn Ọba Aládé ilẹ̀ Àwórì àti gbogbo àwọn Ìjòyè wọn pẹ̀lú àwọn Ìgbìmọ̀ Àwórì Welfare Association of Nigeria (AWAN) látí fún òun ní ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ ti Yewa-Àwórì Royal Scholarship Board (YRSB) tí ó fi kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ O.A.U., Ilé-Ifẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 2009 títí di ọdún 2023 yìí. Ẹ ṣeun!
Ẹ kú oríire, ọ̀gáà mi. May Allah bless you abundantly.
ReplyDelete