Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti sọ pe bi ajọ eleto idibo lorileede Naijiria, Independent National Electoral Commission, INEC ba ṣe magomago, ti wọn ko ṣe ojuṣe wọn ninu eto idibo to n bọ lọna yii, wọn yoo ri ibinu Ọlọrun.
Wolii Ayọdele lo sọrọ naa l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii, nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ẹ to waye niluu Eko.
Nibẹ lo ti sọ pe oriṣiriṣi wahala lo n palẹmọ lẹyin eto idibo apapọ to n bọ lorileede Naijiria laaarin ọjọ mọkanla si asiko yii, to si ni gbogbo aṣeyọri eto idibo naa wa lọwọ ajọ INEC.
Wolii Ayọdele tun fi kun ọrọ rẹ pe wahal nla yoo ṣẹlẹ bi oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour ati APC, Peter Obi ati Bọla Tinubu ba padanu.
"Ko nii ṣi iditẹ-gbajọba kankan ti yoo ṣẹlẹ, ṣugbọn otitọ to wa nibẹ ni pe bi Obi ba padanu ninu eto idibo yii, wahala maa ṣẹlẹ; bẹẹ si ni bi Tinubu ba padanu, wahala yoo ṣẹlẹ.
"INEC lo maa pinnu ọjọ iwaju Naijiria, ṣugbọn bi wọn ba ṣe magomago, wọn yoo ri ibinu Ọlọrun. Ibi ti a ro pe ibo naa yoo lọ, o le ma lọ sibẹ."
No comments:
Post a Comment