ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé Orí-Àrán
Bí gbogbo àwọn ènìyàn bá ń gbọ́ mi lórí Rédíò tàbí èyíkéyìí orí afẹ́fẹ́ ìkéde, mo sábà máa ń gbé oríyın fún Iléeṣé Ìròyìn kan tí wọ́n pè ní Awíkonko.
Ìtumọ̀ Awíkonko nínú èdè Yorùbá jinlẹ̀ púpọ̀. Ìgékúrú ìpèdè Awíkonko-lójú-ọlọ́rọ̀-kọ́lọ́rọ̀-ó-gbọ́ ni Iléeṣé yìí sọ di orúkọ rẹ̀. Bí àwọn Yorùbá bá wá lo èdè yìí, ó túmọ̀ sí pé, àwọn Yorùbá gan-an ni wọn kì í fẹ́ kí àwọn ìwà ìbàjẹ́ inú àwùjọ pa òtítọ́ sísọ lára ní gbogbo ibi tí wọ́n bá wà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá hu ìwà ìbàjẹ́ nínú àwùjọ Yorùbá, wọ́n ní àwọn ìlànà àti ète pẹ̀lú ọgbọ́n tí wọ́n fi ń kọ àwọn ìwà ìbàjẹ́ náà. Bí wọ́n bá ṣe àkíyèsí pé àwọn ẹ̀dá kan gọ sí ìkọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń hùwà ibi, wọ́n lè gbé Eégún Aláwàdà, Gẹ̀lẹ̀dẹ́ tàbí Orò jáde láti kiìlọ̀ àwọn ìwà ìbàjẹ́ náà.
EÉGÚN ALÁWÀDÀ: Èyí ni irúfẹ́ àwọn Eégún kan tí wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n fi máa ń kéde àwọn ohun tí ń lọ nínú àwùjọ wọn. Ìlànà ìfẹ̀dáṣẹ̀fẹ̀ ni wọ́n máa ń lò láti ṣe àpèjúwe àwọn ẹ̀dá tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ náà fún gbogbo ayé gbọ́. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé, bí wọ́n bá ti polongo ìwà búrúkú tí àwọn ẹ̀dá náà hù síta, wọn yóò jáwọ́ nínú ìwà náà. Ìdí tí ó fi jẹ́ pé Egúngún Aláwàdà ni wọ́n máa ń lò ni pé, àwọn ènìyàn kò ní bínú sí irúfẹ́ Eégún bẹ́ẹ̀, nítorí pé, àwàdà ní ń ṣe.
GẸ̀LẸ̀DẸ́: Ẹ̀yà Eégún kan ni èyí náà, tí wọ́n máa ń lò láti fi ṣe ìdánílẹ́kọ̀ọ́, ìdánilárayá àti ìkìlọ̀ ìwà ìbàjẹ́ inú àwùjọ wọn. Ìlànà tí wọ́n ń gbà kéde ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ wọn ní ojú-agbo eré ni Eré Gẹ̀lẹ̀dẹ́ jẹ́. Àwọn Òṣeré Gẹ̀lẹ̀dẹ́ gan-an ni ó yẹ kí a máa pè ní Awíkonko. Ìdí ni pé, kò sí ẹ̀dá inú àwùjọ wọn tó hu ìwà ìbàjẹ́, tí wọn kò lè fi ṣe ẹ̀fẹ̀ lójú agbo eré wọn. Ẹ̀fẹ̀ tí àwọn Gẹ̀lẹ̀dẹ́ máa ń ṣe láwùjọ, ni wọ́n ń pè ní Ẹ̀fẹ̀ Gẹ̀lẹ̀dẹ́, tí ó túmọ̀ sí ẹ̀fẹ̀ tí àwọn Òṣeré Gẹ̀lẹ̀dẹ́ máa ń ṣe.
OHUN TÍ A NÍ LỌ́KÀN GAN-AN NI PÉ Iléeṣẹ́ Ìròyìn Awíkonko kì í fi igbá kan bọ ọ̀kan nínú, bí ó bá di ọ̀rọ̀ nípa ìwà ìbàjẹ́ tí àwọn ènìyàn ń hù nínú àwùjọ. Iléeṣẹ́ Ìròyìn Awíkonko máa ń sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an ní pàtó fún gbogbo àgbáyé.
Mo gbé Òṣùbà káre fún Olóòtú Ìròyìn náà. Mo sì gba àdúrà fún un pé, yóò máa júṣe fún un lágbára Èdùmàrè. Àṣẹ.
©
ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé Orí-Àrán lèmi ń jẹ́
Mo júbà oo
Ìbà Ọlọ́run Èdùmàrè
Ìbà Kábíèsí Ọlọ́tà Odò
Ìbà Ọkùnrin
Ìbà Obìnrin
Ìbà Ọmọdé
Ìbà àgbà
Ìbà Oyún inú
Ìbà Àṣẹ́ẹ̀bí
Ẹ jẹ́ kó yẹ mí oo.
Àṣẹ Èdùmàrè 🙇♂️
No comments:
Post a Comment