Ijọba ipinlẹ Kwara ti bu ọwọ lu awọ ohun elo to wulo f'awọn akẹkọọ patapata kaakiri ipinlẹ naa, ki eto ẹkọ wọn le tubọ rọrun fun wọn lai daamu.
Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii ni ijọba pin awọn iwe ajakọ to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọfa, ati awọn ohun elo miran to le ni ẹgbẹrun meji.
Awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ girama kekere to jẹ t'ijọba lo jẹ anfaani yii
Yatọ si eyi, ijọba tun pin ohun elo ikọṣẹ to le ni ẹgbẹrun kan aabo paali f'awọn ile ẹkọ naa, eyi ti yoo mu iṣẹ rọrun fun gbogbo awọn olukọ ati akẹkọọ lapapọ.
Nigba to n ṣiṣọ loju pinpin awọn ẹbun naa niluu Ilọrin, Gomina AbdulRahmam AbdulRazaq, sọ pe eto ẹkọ jẹ oun logun pupọ, idi toun fi karamasiki ẹ, nitori pe ọjọ ọla awọn ogo wẹẹrẹ lo ṣe pataki soun.
Gomina AbdulRazaq ti oludamọran pataki rẹ, Alaaji Saadu Salau ṣoju fun, sọ pe ijọba ipinlẹ naa ko fẹẹ fi aaye kankan silẹ lai ni idagbasoke ati ilọsiwaju.
No comments:
Post a Comment