Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe ko si ipadasẹyin ninu eto ati ilana to wa nilẹ lori owo naira tuntun ati t'atijọ to wa nilẹ, eyi ti banki apapọ, CBN gbe kalẹ.
Lonii, Ọjọbọ, Tọsidee, ni Aarẹ Buhari sọrọ naa lakoko to n ba gbogbo ọmọ Naijiria sọrọ lori ipinnu rẹ lati ṣatunṣe lori awọn owo naira ti a n na lorileede yii.
Aarẹ Buhari sọ pe lotitọ loun ba gomina banki CBN ṣepade lọdun to kọja, toun si sọ idi pataki ti wọn fi gbọdọ paarọ awọn owo ti a n na ni Naijiria, ati pe oun fọwọ sii pe ki a dẹkun nina awọn owo naa lọjọ kọkanlelọgbọn, osu kinni, ọdun yii.
Siwaju sii lo sọ pe awọn tun ri idi pataki lati fi ọjọ mẹwaa kun owo atijọ naa, ki awọn araalu le da wọn pada si banki.
O ni ẹgbẹrun kan naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati igba naira ni owo ti oun ni ipinnu lati ṣe ayipada wọn, ti ko si si ipadasẹyin lori ẹ.
Ni bayii, Aarẹ Buhari sọ pe ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta naira ti a n na tẹlẹ ko nii wulo mọ, ṣugbọn awọn yoo da igba naira ti a n na tẹlẹ pada sita f'awọn araalu lati na, titi di oṣu kẹrin, ọdun yii.
"Lati le f'opin si wahala t'awọn eeyan n koju, paapaa araalu, mo ti fun CBN ni aṣẹ lati da awọn owo igba naira ti tẹlẹ pada sita, ki awọn eeyan ṣi maa na wọn lọ.
Bakan naa ki awọn owo tuntun, ẹgbẹrun kan, ẹẹdẹgbẹta ati igba naira naa pẹlu awọn owo ti a ma maa na titi ti ọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin, ọdun 2023.
No comments:
Post a Comment