Idibo 2023: Ẹgbẹ oṣelu APC ati Tinubu maa lulẹ gbẹyin nitori Wike - Wolii Ayọdele ju bọmbu ọrọ sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 12, 2023

Idibo 2023: Ẹgbẹ oṣelu APC ati Tinubu maa lulẹ gbẹyin nitori Wike - Wolii Ayọdele ju bọmbu ọrọ sita


Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Ayọdele ti sọ pe oludije s'ipo aarẹ ti gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ba ṣagbatẹru ẹ lọdun 2023 yoo lulẹ gbẹyin ni.
 
Wolii Ayọdele sọ pe Wike kan fẹẹ da rukerudo silẹ fun oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Ahmẹd Tinubu lasan ni.
 
Gbajugbaja Wolii naa lo sọrọ yii ninu atẹjade ti oludamọran pataki rẹ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Oluwatosin Ọṣhọ gbe jade lonii, ọjọ Aiku, Sannde.
 
O ni o ṣeni laanu wi pe Wike n fi ọjọ ọla rẹ ninu eto oṣelu tafala, pẹlu awọn igbesẹ to n gbe lẹnu ọjọ mẹta sẹyin.
 
“Ẹgbẹ oṣelu APC ati Tinubu maa lulẹ n'ipinlẹ Rivers. Bi Wike ṣe n ṣagbatẹru Tinubu yoo jẹ ajalu, nitori pe ẹnikẹni ti gomina naa ba tẹle yoo lulẹ patapata
.
 
“Wike n fi ọjọ iwaju rẹ ninu eto oṣelu ṣere, eyi yoo si ta epo si aṣọ ala rẹ. Awọn eeyan rẹ ko nii gbọran sii lẹnu, nitori pe o ti gun igi re kọja ewe.’’
 
Bakan naa ni Wolii Ayọdele tun ṣe ikilọ nla fun ajọ eleto idibo orileede Naijiria, iyẹn National Electoral Commission, INEC, lori eto idibo to n bọ yii, to si loun ri awuruju to fẹẹ ṣẹlẹ nipasẹ ajọ naa.
 
O kọminu lori ẹrọ BVAS ti ajọ INEC fẹẹ fi ṣeto idibo yii, to si lawọn kan yoo gbabọdi nitori pe wọn fẹẹ dabaru aṣeyọri ẹtọ idibo apapọ ọdun 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI