Ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited ti kede sita wi pe ẹkunwo ti wa lori awọn ilẹ ati dukia ti wọn n ta lawọn agbegbe ti wọn ti n ta ilẹ ati dukia kaakiri orileede Naijiria.
Ninu atẹjade ti alakoso eto amuṣẹṣe (Director of Operations), Ọgbẹni Ifẹoluwa Daniel fi ranṣẹ s'AWIKONKO laipẹ yii, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe bi nnkan ṣe ri lasiko yii lo fa a, ati pe fun idagbasoke ni.
Wọn ni latari bi ijọba ipinlẹ Ogun ṣe bu ọwọ lu ileeṣẹ wọn ti wọn fi n ṣiṣẹ agbẹ ati ọgbin, iyẹn Pelican Greenish Acres Farm Estate lo fa a ti wọn ṣe fi owo kun owo ti wọn n ta ilẹ wọn, ki awọn onibara le tubọ jẹ afaani idagbasoke agbegbe naa.
Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ọpọ awọn onibara to le ni ẹgbẹrun ni wọn ti n wa lati ba wọn dowo pọ lori eto iṣẹ agbẹ ti wọn dawọ le.
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ eto ati ilana lori bi opopona yoo ṣe gba inu ọgba naa, ati awọn kọta ti omi, agbara yoo maa gba kọja fun igbadun awọn to n wa lati dowopọ.
"Lọwọlọwọ bayii, a ti ni awọn onibara to le ni ẹgbẹrun kan ninu awọn onibara ileeṣẹ Pelican Brief Estate, to wa ni Kọbapẹ, ti wọn ti n jẹ anfaani 'Greenish Acres Farm Estate', nitori bi wọn ṣe ba wa dowopọ.
"Akọsilẹ wa ti f'idi rẹ mulẹ pe ida ọgọrin awọn to ti n jẹ anfaani ilẹ Greenish Acres Farm Estate wa, ni wọn jẹ onibara wa tẹlẹ ni Pelican Brief Estate ati Pelican Valley."
Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe b'awọn eeyan ati onibara wọn tẹlẹ ṣe n ra ilẹ, ti n kọja ilẹ ti wọn ni lagbegbe naa, nitori pe wọn ko ni ilẹ to to eyi t'awọn eeyan n beere fun.
Idi ree ti wọn fi kede sita pe awọn yoo bẹrẹ ipele keji laipẹ, lẹyin ti awọn ba ti pari ipele akọkọ, paapaa nitori pe wọn ko fẹẹ sare dawọ le ipele keji bayii, ayafi bi ipele akọkọ ba yọri.
Wọn ni ẹkunwo yoo gun ori awọn ilẹ wọn, bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2023. Ẹkunwo naa ree;
1. A plot of Land - ₦3,500,000
2. Development Levy - ₦250,000
3. Survey - ₦200,000
4. Legal and Documentation Fee - ₦50,000
5. Application form - ₦10,000
Total: ₦4,010,000
No comments:
Post a Comment