Gbogbo awọn to ṣe ikọlu s'awọn ile ifowopamọ ni Ṣagamu yoo foju winna ofin - Dapọ Abiọdun ṣeleri (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 22, 2023

Gbogbo awọn to ṣe ikọlu s'awọn ile ifowopamọ ni Ṣagamu yoo foju winna ofin - Dapọ Abiọdun ṣeleri (Fọto)


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti ṣe ileri wi pe gbogbo awọn to ṣe ikọlu s'awọn ile ifowopamọ ati ileeṣẹ panapana ni yoo foju winna ofin patapata, lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
 
Dapọ Abiọdun lo sọ eyi lakoko to ṣe abẹwo si awọn banki ati ileeṣẹ panapana ti awon tọọgi ati olufẹhonuhan ṣe ikọlu si, ti wọn si tun dana sun.
 
Yatọ si pe awọn tọọgi dana sun awọn banki, mọto ati ọpọ dukia, wọn tun lo anfaani rẹ lati fi ji owo ko, ti wọn si tun dana sun awọn iwe to ṣe pataki nibẹ pẹlu.
 
Gomina Abiọdun lakoko to n kọminu, o loun mọ pe kii ṣe awọn olufẹhonuhan lo ṣe ikọlu, ti wọn si tun dana sun banki, bi ko ṣe awọn tọọgi ti wọn ti n wa ọna lati da wahala silẹ.
 
Bẹẹ lo sọ pe oun ti sọ f'awọn agbofinro lati rii pe ọwọ tẹ gbogbo awọn to ṣiṣẹ buruku naa, toun si nigbagbọ pe laipẹ, wọn yoo ko si gbaga ọlọpaa.
 
Diẹ ree lara awọn fọto abẹwo ọhun:





















No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI